Aye le! Iya atọmọ to n ṣe 'Yahoo-Yahoo' ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 12, 2021

Aye le! Iya atọmọ to n ṣe 'Yahoo-Yahoo' ha o


Ojọ kẹwaa, oṣu ti a wa yii, iyẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ijẹta lọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣẹ owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) tẹ awọn afurasi oni jibiti ori ayelujara ti wọn tun n pe ni Yahoo-Yahoo, eyi ti iya atọmọ rẹ naa wa lara wọn.
 
Margaret Sylvester, Lucky Ebhogie, Richman Kas Godwin, Israel Justin ati Precious Iwuji lorukọ awọn mẹrin tọwọ tẹ naa, ti wọn si ni ko si eyi to niṣẹ meji ninu wọn, to kọja jibiti ori ayelujara.
 
Agbegbe Sabo to wa nilu Kaduna, ipinlẹ Kadun lọwọ palaba wọn ti segi, lẹyin ofin toto ti wọn lawọn oṣiṣẹ EFCC ṣe.
 
Wilson Uwujaren nigba to n sọrọ sọ pe orukọ olorukọ lawọn eeyan naa fi n lu jibiti, ti wọn si ti gba obitibiti owo lọwọ awọn onibara wọn pẹlu ọgbọn ayederu ifẹ ori ayelujara. 
 
A gbọ pe orukọ awọn ẹṣọ ologun ilẹ Amẹrika ni wọn fi n lu awón eeyan wọn ni jibiti ko to di pe aṣiri wọn tu sita.
 
Wọn ni apo ile ifowopamọ mama rẹ ni Ebhogie lo lati fi gba owo naa wọle, to si lọ ra mọto bọginni Mercedes Benz GLZ ti owo rẹ ko din ni miliọnu meje naira pẹlu apo owo mama rẹ lọgbọn ọjọ, oṣu keje to kọja.

Ni ti Iwuji, tọwọ tẹ, a gbọ pe ṣe lo ta ikanni fesibuuku rẹ fun ọmọ Yahoo, pẹlu erongba lati maa jẹ ki wọn fi wa awọn ti wọn yoo lu ni jibiti, ṣugbọn ti aṣiri pada tu sita.

Uwujaren sọ pe laipẹ lawọn eeyan naa yoo foju ba ile-ẹjọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI