Idaamu de bawọn to n gbe mọto sibi ti ko yẹ ni Kwara, nitori ofin tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 12, 2021

Idaamu de bawọn to n gbe mọto sibi ti ko yẹ ni Kwara, nitori ofin tuntun


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn to n gbe mọto sibi ti ko yẹ nipinlẹ naa yoo bẹrẹ si i foju winna ofin, bẹẹ lawọn to n da ilẹ ilẹ ati idọti sibi ti ko yẹ naa yoo tun gba idajọ to ba tọ si wọn.
 
Wọn lawọn ti ṣetan lati mu ọrọ eto imọtoto to bori arun mọlẹ lokunkundun.
 
Ana ni ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣẹ iṣẹ ati ọkọ; pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ayika ati agbegbe, to fi mọ ileeṣẹ to n ri sọrọ okoowo, Enterprise tọwọ bọ iwe adehun lati ṣiṣẹ papọ fun alaafia lati jọba.
 
Kọmiṣanna mẹjẹẹta, Onimọ-ẹrọ Rotimi Ilyas; Arabinrin Oluwatobi Rẹmilẹkun Banigbe ati Hajia Arinmọla Lawal ṣe ipolongo lati kilọ fawọn araalu wi pe ki wọn dide eto imọtoto ayika ati agbegbe wọn.
 
Lara awọn to tun wa nibẹ ni alaṣẹ ati oludasilẹ KWARTMA, Alaaji Yeekeen Babatunde Bello; alaga KWARMA, Onọrebu ọlakalẹ Olọjẹ; ọga agba KWARMA, Onimọ-ẹrọ Jibrin ati Onórebu Razaq Jiddah.
 
Nibẹ ni wọn ti gbawọn eeyan lamọran wi pe ki wọn tete tun ayika ati agbegbe wọn, ki wọn si gbe gbogbo awọn ohun ti wọn gbe sibi ti ko yẹ,bii ṣọọbu alagbeka, mọto atawọn mi in kuro nibi ti ko ba oju mu to, ko to di pe igbesẹ ofin bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI