Ayédèrú ọ̀gá ọlọ́pàá meji wọ gàù ní Delta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 5, 2021

Ayédèrú ọ̀gá ọlọ́pàá meji wọ gàù ní Delta


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ awọn meji kan, ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa fi orukọ ọga ọlọpaa lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri igboro lọ.
 
Bankọle Ọdunsi ati Samuel Idowu la gbọ pe yatọ si pe wọn n fi orukọ ọga ọlọpaa lu jibiti yii, wọn tun n ṣowo ibọn fawọnn ọdaran kaakiri ilu.
 
Ana ti i ṣe Ọjọru, Wẹsidee ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta foju awọn mejeeji pẹlu awọn mẹtadinlogun mi-in han fawọn akọroyin niluu Asaba.
 
Wọn ni ṣe ni wọn n sọ fawọn eeyan kaakiri wi pe ipo ọga lawọn wa nidi iṣẹ ọlọpaa, iyẹn ipo igbakeji, Assistant Inspectors of Police.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Ali nigba to n sọrọ sọ pe awọn ọlọpaa RRS lo rọwọ to awọn mejeeji lakooko ti wọn n yẹ awọn mọto wo kaakiri.
 
O ni inu mọto ayọkẹlẹ Ford kan ni wọn ti da wọn duro, ti awọn mejeeji si wọ aṣọ ọlọpaa sọrun lori afara tiluu Asaba. Nibẹ ni wọn tun ti gba ayederu ibọn lọwọ wọn.

Lakooko ti wọn n kọkọ fọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn ni ọlọpaa lawọn, ṣugbọn nigba ti ibeere naa pọ ju, lo mu ki wọn jẹwọ pe awọn kan n fi aṣọ naa boju lasan ni.
 
Nigba tawọn mejeeji n jẹwọ ẹṣẹ wọn, wọn ni loootọ awọn ki i ṣe ọlọpaa, ṣugbọn tawọn n ṣiṣẹ fawọn ọlọpaa gẹgẹ bi i olofintoto. Wọn ni banki kan to wa ni Lagos Island lawọn ti n ṣiṣẹ.
 
Wọn tun sọ pe ọga awọn lo ran wọn niṣẹ lati gbe mọto naa lọ fun ẹnikan nipinlẹ Imo, ko to di pe ọwọ tẹ awọn. Bẹẹ ni wọn sọ pe aṣiṣe kan ṣoṣo tawọn ṣe ni pe awọn wọ aṣọ ọlọpaa sọrun.
 
Bakan naa nigba ti wọn jẹwọ ibi ti wọn ti ri awọn aṣọ naa ji ko, wọn ni ibi ti wọn maa n ko awọn aṣọ naa si lawọn ti lọ ji wọn ko, lai mọ pe aṣiri maa pada tu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI