Beeyan ba de ọgba ẹwọn awọn ọlọpaa ti agbegbe Orile-Iganmu nipinlẹ Eko, to ri i bi ibẹ ṣe ri, bi iya ṣe n jẹ awọn ẹlẹwọn, ko ni gbadura lati ri ogun ẹjọ tabi ogun adunrunmọ laye.
Ohun to daju ni pe bawọn kan ṣe n jiya ẹṣẹ wọn, bẹẹ lawọn mi in jiya ẹṣẹ aimọdi lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, bẹẹ lo jẹ pe ija lo gbe ẹlomi in dọgba ẹwọn.
Ibi ti ẹ n wo yii ni ọgba ẹwọn tawọn ọlọpaa maa n fi awọn to ba ko sakolo wọn pamọ si, digba ti wọn yoo fi ko wọn lọ sile-ẹjọ.
Oju kan ṣoṣo lawọn to ba wa nibẹ ti maa n wẹ, ti wọn yoo yagbẹ, bẹẹ ni wọn yoo tun jẹun, yatọ si eyi, ibẹ naa ni wọn n sun si, ti oorun buruku to wa nibẹ si le tete ge ẹmi wọn kuru.
Inu ọgba ẹwọn yii kan naa ni wọn ti n jẹ ounjẹ ti wọn ba gbe fun wọn.
Ẹni to ba sọ pe toun ko to laye, tabi iṣoro toun ni ga ju tẹnikan lọ, to ba de ibi ti a n sọ yii, yoo tun dupẹ lọwọ Ọlọrun ti ko jẹ ko ri ogun ẹjọ.
Bẹẹ, ijọba orilẹ-ede yii nilo lati tun awọn ọgba ẹwọn to wa kaakiri orilẹ-ede yii ṣe.
Diẹ ree lara awọn fọto naa:
No comments:
Post a Comment