Aarẹ Muhammadu Buhari ti orilẹ ede Naijiria ti sọ pe digbi lara aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bọla Ahmed Tinubu wa, ko si ṣaisan kankan, gẹgẹ bi awọn kan ṣe gbe iroyin naa jade.
Irọlẹ ana, Ọjọbọ, Tọsidee ni Aarẹ Buhari kede ọrọ naa sita wi pe oun ti lọ ṣe abẹwo si Tinubu lati mọ eyi to jẹ otitọ ninu iroyin to n lọ kaakiri.
O ni boun ṣe ri Tinunu, ṣaka ni ara rẹ da, oun ko si ri aisan kankan loju rẹ, ṣugbọn to sọ pe baba naa lọ fun ara rẹ ni isinmi nilu Oyinbo lasan ni.
Nibẹ lo ti wa gba awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ Naijiria lamọran wi pe ki wọn ma ṣe gba awọn iroyin ẹlẹjẹ to n jade lori ikanni ayelujara gbọ, bi ko ṣe eyi to ba wa lawọn ibi to ṣee fẹsẹ mulẹ daadaa
No comments:
Post a Comment