Gbajumọ oniṣowo dero Kirikiri l'Ekoo, awọn ọmọ rẹ kekeeke mẹta lo n ko ibasun fun karakara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 14, 2021

Gbajumọ oniṣowo dero Kirikiri l'Ekoo, awọn ọmọ rẹ kekeeke mẹta lo n ko ibasun fun karakara


Ile-ẹjọ majisireeti to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko ti ju gbajugba oniṣowo kan, Emeka Orisakwe si atimọle lori ẹsun wi pe o n fipa ba awọn ọmọ rẹ kekeeke laṣepọ karakara lojoojumọ.
 
Ọmọ ọdun mẹtalelogoji ni wọn pe Emeka. Agbegbe Maza Maza, ni Amuwo Ọdọfin, Eko lo n gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ ọhun.
 
Bo tilẹ jẹ pe Emeka bẹbẹ fun oju aanu, ṣugbọn ti Onidajọ Ejiro Kubeinje, sọ pe ko i alaye kankan lẹnu, ati pe ko ṣi lọ maa gbadun ara rẹ ni ọgba ẹwọn Kirikiri titi digba ti igbẹjọ yoo waye.
 
Agbẹjọro ọlọpaa, ASP Bisi Ogunlẹyẹ, to fẹsun kan Emeka sọ pe osu karun si oṣu keje, ọdun lo uwa naa ninu ile ẹ.
 
O ni ọmọ ọdun meje, ọmọ ọdun mẹfa ati ọmọ ọdun mẹrin lawọn ọmọ bibi inu rẹ mẹta to n ko ibasun fun karakara lojoojumọ bo ṣe wu.
 
Onidajọ Kubeinje wa a paṣẹ pe ko ṣi lọ farapamọ si ọgba ẹwọn kirikiri titi di ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun yii ti igbẹjọ yoo tun pada waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI