Eemọ! Odaju abiyamọ ju ọmọ oojọ sori akitan ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 9, 2021

Eemọ! Odaju abiyamọ ju ọmọ oojọ sori akitan ni Kwara


Bo tilẹ jẹ pe titi dakooko ti a kọ iroyin yii tan, ni ko ti i sẹni to le sọ obinrin to ju ọmọ rẹ, ọmọ oojọ sori akitan niluu Patigi, ipinlẹ Kwara, sibẹ, epe rabandẹ-rabandẹ lawọn to ri ọmọ ikoko naa n gbe iya rẹ ṣẹ.
 
Ojọ Eti, Furaidee to kọja yii la gbọ pe awọn ara Patigi, nijọba ibilẹ Patigi ri ọmó oojọ naa lori akitan, to n sunkun kikan-kikan lai mọ ẹni to gbe e ju sibẹ.
 
Bi wọn ṣe ri ọmọ naa lo mu ki wọn sare ranṣẹ awọn oṣiṣẹ eleto aabo Sifu Difẹnsi lati wa a wo iṣẹlẹ kayeefi to gbẹnu tan. 
 
Obinrin ni wọn pe ọmọ tuntun naa, ti ko ti i mu ọmu ri, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 
A gbọ pe agboole kan ti wọn pe ni Dokoyorigi niluu Patigi ni wọn ju ọmọ naa danu si i.
 
Babawale Zaid Afọlabi, to jẹ alukoro ileeṣẹ Sifu Difẹnsi sọ pe aarọ kutu ni wọn ri ọmọ yii, ati pe diẹ lo ku ki ẹmi bọ lara rẹ, ko to di pe wọn sare gbe e lọ si ọsibitu fun itọju.
 
Afọlabi sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọsibitu ti wọn gbe ọmọ ọhun lọ, iyẹn Tsado Racheal ti ṣeleri wi pe oun yoo gba ọmọ naa tọ, titi yoo fi dagba labẹ ofin.
 
Bẹẹ lo lawọn ti n gbe igbesẹ lati ri obinrin to ju ọmọ naa si akitan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI