Sunday Igboho! Idi pataki ti Obasanjọ fi lọ si Benin gan-an ree - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, August 9, 2021

Sunday Igboho! Idi pataki ti Obasanjọ fi lọ si Benin gan-an ree


Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe Aarẹ tẹlẹri lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Obasanjọ lọ silẹ Olominira Benin, ta a si gbọ pe nitori olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ to wa lahamọ wọn lo ṣe lọ.
 
Fun bi ọpọlọpọ wakati la gbọ pe Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Aarẹ orileede Benin, Patrice Talon fi tilẹkun mọri lati ṣepade idakọnkọ lori ọrọ Adeyẹmọ, ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho.
 
Laarin ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹjọ yii l’Ọbasanjọ gbera irinajọ lọọ siluu Zanzibar, lorileede Tanzania, fun apero pataki kan, wọn ni bo ṣe n dari bọ, ilu Port-Novo, ti i ṣe olu-ilu ati ibujokoo ijọba orileede Olominira Benin lo balẹ si, taara lo si lọọ ṣabẹwo si Aarẹ wọn lọhun-un.
 
Ba a ṣe gbọ, wọn l’Ọbasanjọ kọkọ lo anfaani naa lati ba Aarẹ ilẹ Bẹnẹ tẹlẹ ri, Ọgbẹni Nicephore Soglo, kẹdun ti iyawo rẹ, Roseline Soglo, to doloogbe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, to kọja yii.
 
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ hulẹhulẹ ọrọ tawọn agbaagba meji naa ba ara wọn sọ labẹ aṣọ, Amugbalẹgbẹẹ fun Ọbasanjọ lori eto iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ lọga oun tilẹkun mọri ṣepade pẹlu Aarẹ ilẹ Bẹnẹ, ṣugbọn oun o le sọ ju bẹẹ lọ lasiko yii na.
 
Amọ ṣa, Akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Kọla Ọmọlolu, ti sọ pe ẹgbẹ naa n ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu Baba Ọbasanjọ, lori ọrọ Sunday Igboho, ati pe didun lọsan yoo so laipẹ.
 
“Ẹ jẹ ki n sọ fun yin ni taarata pe ẹgbẹ Afẹnifẹre ati aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ jọ n ṣiṣẹ papọ lati da ireti awọn ọmọ Naijiria pada, paapaa awọn ọmọ Oduduwa, o si daju pe aṣeye lalakan yoo ṣ’epo lori ọrọ yii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI