Èmi náà fẹ́ẹ́ jáde du ipò alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lápapọ̀ - Oyinlọlá jẹ́wọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 25, 2021

Èmi náà fẹ́ẹ́ jáde du ipò alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lápapọ̀ - Oyinlọlá jẹ́wọ́


Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla ti sọ pe oun naa ni erongba lati jade du ipo alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lapapọ, lati le mu ẹgbẹ naa tẹsiwaju.
 
Oyinlọla to tun jẹ akọwe tẹlẹri fun ẹgbẹ naa lapapọ lo sọ eyi di mimọ lonii, Ọjọru, Wẹside, niluu Oṣogbo lakooko to n dahun ibeere lori redio kan ti wọn ti gba a lalejo, eyi ti wọn fi n saami ayẹyẹ ọgbọn ọdun ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ.
 
Nibẹ lo ti sọ pe jijade lati du ipo naa pin si ọna meji, to si ni ọna akọkọ ni bi wọn ba pin ipo naa si ilẹ Yoruba, ti ekeji yoo si jẹ pe bawọn alẹnulọrọ ba le bu ọwọ lu oun.
 
O ni nipa awọn iriri oun lẹka eto oṣelu ati iṣejọba, paapaa boun ti ṣe dari ijọba ipinlẹ Eko lasiko ologun, ati boun tun ṣe jẹ gomina alagbada kẹta nipinlẹ Ọṣun, oun yoo le ṣakoso ẹgbẹ PDP lai si kudiẹ-kudiẹ.
 
Siwaju lo sọ pe awọn to n ba oun lorukọ jẹ nitori wi pe oun lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọdun 2014 kan n wa awawi lasan ni, ati pe awọn aṣeyọri oun nijọba ko ṣee fọwọ rọ ti sẹyin. 
 
Bẹẹ lo sọ pe oun ni awọn akọsilẹ rere pẹlu boun ṣe sakoso ipinlẹ meji ọtọọtọ lorilẹ-ede yii, ti ko si sẹni to fẹsun jibiti tabi aṣemaṣe kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI