Gbajumọ akọroyin, Laide Gold fẹẹ gbe magasiini Aṣa ati Iṣe jade l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 12, 2021

Gbajumọ akọroyin, Laide Gold fẹẹ gbe magasiini Aṣa ati Iṣe jade l'Ekoo

 
Bi ẹ ba pe e ni akọroyin, ẹ ko purọ, bi ẹ si pe e ni sọrọsọrọ, bẹẹ naa lo ri. Laide Gold lẹni ti a n sọ yii.
 
Odu ni Laide Gold lagboole akọroyin ati sọrọsọrọ nipinlẹ Eko, paapaa lorilẹde Naijiria, ẹni to tun fẹran igbelarugẹ awọn aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba kaakiri agbaye.

Laide Gold, ẹni to n ṣe eto nileeṣẹ redio Bond FM nipinlẹ Eko ti tukọ oriṣiriṣi awọn iwe iroyin oloyinbo ati Yoruba kaakiri Naijiria ati apakan lagbaye.
 
Bẹẹ lo tun jẹ oludasilẹ magasiini to pe ni ODUDUWA QUEST, eyi to fi n gbe aṣa ati iṣẹṣe larugẹ. Awọn kan a tiẹ maa pe e ni Yeye Aṣa.
 
Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun Laide Gold lati ṣe ikojade magasiini rẹ tuntun to pe ni GLOBAL QUEST MAGAZINE.
 
Magasinni naa to n fi n ṣe agbelarugẹ aṣa, iṣe ati irin ajo afẹ kaakiri agbaye ni wọn fẹẹ ko jadelọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ ti a wa yii niluu Eko.

A gbọ pe awọn eekan-eekan, awọn eeyan jankan-jankan ati ọtọluku lawujọ wa, paapaa awọn agba gbajumọ oṣere tiata ati amuludun loriṣiriṣi ni wọn yoo wa nibẹ lọjọ naa.
 
Saaju akooko yii ni Laide Gold ti da ẹgbẹ tiata kan to pe ni Oduduwa Quest Troupe silẹ lọdun 2005, pẹlu erongba lati lọ kaakiri ilẹ Oduduwa nipa ṣiṣe awari awọn itan to rọ mọ idasilẹ ati awọn iṣẹṣe wọn.

Alaga ati oludasilẹ ileeṣẹ Finecoats Paints, Omọwe Aderẹmi Awode, ati alaga agbegbe ijọba ibilẹ idagbasoke Ojuwoye-Odi-Olowo, Ọnọrebu Oluṣọla Ajala Rasak ni wọn yoo tukọ eto ọjọ naa.
 
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ awọn olootu iwe iroyin Yoruba, iyẹnGuild of Yoruba Editors, Ogbẹni Taofeek Afọlabi gbe jade, lo ti sọ pe pupọ alẹnulọrọ lawujọ ni wọn ti gbaradi lati wa nibi ayẹyẹ lọjọ naa. 
 
Ọgbẹni Afọlabi lo jẹ ka mọ pe gbagede kan to wa ni ijọba ibilẹ idagbasoke Ojuwoye-Odi-Olowo to wa lagbegbe Ilupeju, Eko ni ayẹyẹ naa yoo ti waye pẹlu awọn eto ọlọkan-o-jọkan ti wọn ti la kalẹ.

Lara awọn ti yoo tun wa nibẹ ni Oloye Fakunle Oyesanya, to jẹ Aarẹ ileeṣẹ Adaci Nigeria; Dare Adeṣọpẹ, Aarẹ ẹgbẹ OPC Reformed. Bẹẹ lawọn ọba alaye bi i Ọba Samuel Awoyẹmi Oroja, Onimẹran tilu Mẹiran; Ọba Rilwan Oluwalambẹ, Olojokoro tilu Ojokoro, atawọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI