Ile Keu ni ọmọ ọdun meje kan n lọ, ki baba agbalagba to fipa tan an wọle lati ba a laṣepọ tipatipa, ṣugbọn o ti dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 12, 2021

Ile Keu ni ọmọ ọdun meje kan n lọ, ki baba agbalagba to fipa tan an wọle lati ba a laṣepọ tipatipa, ṣugbọn o ti dero atimọle


Baba agbalagba, ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan, Ibrahim Bello, ti wọn fẹsun kan wi pe o fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun meje kan laṣepọ ti dero atimọle bayii.
 
Se la gbọ pe asiko ti ọmọ naa kuro nile, to si n lọ si ile keu ni Ibrahim pe e wi pe oun fẹẹ ran an niṣẹ, to si ṣe bẹẹ tan an wọnu ile, nibi to ti fipa ko ibasun fun karakara.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Saminaka, nijọba ibilẹ Yola South, ipinlẹ Adamawa niṣẹlẹ ọhun ti waye lopin ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ Satide, Abamẹta.
 
Wọn ni ṣe ni ọmọ naa ati aburo rẹ n lọ si ile keu, ti wọn ti maa n kọ ẹkọ nipa kuraani, ko to di pe Ibrahim pe e pe ko wa, to si ni ki aburo rẹ maa lọ, yoo wa ba a.

Igba ti wọn ni aburo ọmọ ọdun meje naa ṣetan ni ile keu, to pada sile, ni mama wọn beere pe ẹgbọn rẹ n kọ, to si ni ko tẹle oun lọ, ati pe ẹnikan to n jẹ Ibrahim lo pe e nigba tawọn n lọ.

Eyi lo jẹ ki obinrin naa pariwo sita wi pe kawọn ara adugbo gba oun. Nibi ti ariwo naa ti n lọ lọwọ, lo ti ta si Ibrahim leti, to si sare ti ọmọ ọhun jade lati maa lọ sile.

Eyinkule ile naa la gbọ pe Ibrahim gba salọ lai jẹ kẹnikẹni mọ ibi to wa. Idi ree ti wọn fi lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn gbe igbesẹ lati wa a.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Suleiman Nguroje to firoyin naa to wa leti sọ pe alẹ ọjọ Mọnde to kọja yii lọwọ awọn tẹ Ibrahim nigba to yọ wa sile lati ko ẹru rẹ, ko si na papa bora patapata.
 
AWIKONKO gbọ pe Ibrahim ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe iya ọmọ naa kan fẹẹ fi irọ nla yii ba oun lorukọ jẹ lasan ni.
 
Wọn ni Ibrahim ti fẹ iyawo kan tẹlẹ, to bimọ mẹrin fun un, ṣugbọn ti obinrin naa sa fun un nigba to gbọ pe Ibrahim fun aburo rẹ loyun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI