Gbigba owo ori fẹẹ gbọna miran yọ ni Kwara lakọtun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

Gbigba owo ori fẹẹ gbọna miran yọ ni Kwara lakọtun


Lọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii nijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq bura fun igbimọ ẹlẹni meje kan ti yoo ṣabojuto pipa owo sapo ijọba dide.
 
Awọn naa ni Ọgbẹni Banigbe Rotimi Williams, alaga; Pasitọ Ọlagunju Felix, akọwe; Ọgbẹni Ibrahim Musa, Malamu Ibrahim Ahmed, Ọgbẹni Sulyman Shehu Adejumọ, Ọgbẹni Salahudeen Isiaaq, ati Ọgbẹni Mọshood Tijani ti wọn jẹ ọmọ igbimọ.
 
Ohun ti a gbọ ni pe awọn igbimọ yii ni yoo ṣiṣẹ lori awọn ibi idanilẹkọọ ara ọtọ fun awọn ile ẹkọ giga, iyẹn Advanced Coaching Centres and Private Tertiary Institutions kaakiri ipinlẹ ọhun.
 
Nigba to n bura fawọn igbimọ yii ninu ọfiisi rẹ, Kọmiṣanna fọrọ ile ẹkọ giga, Senior Ibrahim Sulyman Esq, ẹni ti akọwe agba, Hajia Hafsat AbdulRahman, ṣoju fun gba awọn eeyan naa lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ lai ṣoju saaju ẹnikẹni.
 
Lara awọn ohun ti igbimọ naa yoo bojuto ni lati mọ awọn ti wọn n ṣe idanilẹkọọ lọna ti ko ba ofin mu ninu awọn ile ẹkọ giga aladani; lati mọ awọn to n san owo ori wọn deede lai jẹ gbẹse, ati bẹẹbẹẹlọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI