Ikunlẹ abiyamọ o! Banki FCMB gbina lojiji, ori lo ko awọn eeyan yọ lọwọ iku ojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 12, 2021

Ikunlẹ abiyamọ o! Banki FCMB gbina lojiji, ori lo ko awọn eeyan yọ lọwọ iku ojiji


Bi ki ba a ṣe ori to ko awọn eeyan yọ lọwọ iku ojiji ni, boya ohun ti a n kọ yii kọ lao ba maa kọ, pẹlu bi gbajugbaja banki FCMB, ẹka tiluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ṣe gbina lojiji, to si jo dukia olowo iyebiye kọja sisọ.
 
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Murtala Mohammed Road to wa nilu Ilọrin ni banki, First City Monument Bank naa wa.
 
Nnkan bi aago mẹta kọja ogun iṣẹju, ana, Ojọru, Wẹsidee la gbọ pe ina naa deede ṣẹyọ lojiji, to si mu kawọn to wa nitosi sa asala fun ẹmi ara wọn.

Gbogbo awọn oṣiṣẹ banki naa, to fi mọ awọn onibara wọn la gbọ pe wọn ko duro de ki ina ọhun ka wọn mọbẹ, ko to di pe wọn ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana lati pana yii. 
 
Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn oṣiṣẹ panapana ti sare debẹ, iyẹn lẹyin iṣẹju mẹjọ ti ina naa bẹrẹ, ti wọn si dawọ rẹ duro.

Apa kan to sunmọ ile igbọnsẹ banki yii la gbọ pe ina naa ti bẹrẹ, to si mu kawọn alakoso banki kede wi pe awọn ti tilẹkun wọn titi di oni, Ojọbọ, Tọside ti wọn yoo bẹrẹ iṣẹ pada lakọtun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI