Nítorí ìgbéyàwó kóòtù, Paul Okoye {P-Square}, kó sínú wàhálà nlá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 23, 2021

Nítorí ìgbéyàwó kóòtù, Paul Okoye {P-Square}, kó sínú wàhálà nlá


Lasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu wahala ati idaamu nla ni gbajugbaja olorn takasufee nni, Paul Okoye, ọkan lara awọn ibeji P-Square wa, lori bi iyawo rẹ, Anita Okoye ṣe gbe e lọ sile-ẹjọ, to si n beere owo rẹpẹtẹ lọwọ ẹ.

Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin ni iroyin ọhun ti kọkọ jade sita, nibi ti Anita ti n sọ pe oun ti n palẹmọ lati kọ Okoye, to si loun ti ko gbogbo awọn ọmọ wọn mẹtẹẹta lọ siluu Oyinbo, iyẹn ilẹ Amẹrika.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Anita fẹsun kan Okoye, ti wọn jọ ṣe ayẹyẹ igbeyawo alarinrin lọdun 2014 niluu Port-Harcourt, wi pe o n yan oun jẹ, ati pe oun ko nifẹẹ rẹ mọ, ki onikaluku maa lọ lọtọọtọ.
 
Ninu iwe ẹsun naa, to jade sori ikanni ayelujara ni Anita ti n sọ pe oun fẹ ki Okoye maa foun ni ẹgbẹrun mẹẹdogun owo dọla, iyẹn miliọnu mẹjọ din diẹ naira, loṣooṣu lati maa fi tọju awọn ọmọ wọn ti wọn wa nile-ẹkọ l'Amẹrika.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọdun 2017 ni lawọn mejeeji bi akọbi ọmọ wọn, Andre, ti wọn si tun pada bi ibeji lẹyin rẹ, Nadia ati Nathan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI