Nítorí fíìmù Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ tí mo kópa nínú ẹ̀, ó kù díẹ̀ kí wọ́n pa mí danù - Lálùdé sọ̀rọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 3, 2021

Nítorí fíìmù Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ tí mo kópa nínú ẹ̀, ó kù díẹ̀ kí wọ́n pa mí danù - Lálùdé sọ̀rọ̀


Bi wọn ba n sọ nipa awọn to sọ iṣẹ tiata di irọrun, wọn ko gbọdọ fọwọ rọ Ọgbẹni Fatai Adekunle Adetayọ sẹyin rara. Ko fẹẹ si awọn ololufẹ tiata to mọ orukọ rẹ yatọ si orukọ to n jẹ ninu fiimu agbelewo. Bi ẹ ba pe e ni Lalude Oodua, oun lẹ n ke si, bi ẹ si pe e ni Lalude Ẹkun, ẹnikan ṣoṣo naa lẹ n darukọ. Lara awọn to si sọ ipa babalawo, oloogun ati jagunjagun di irọrun patapata nidi ere tiata ni Lalude. 
 
Laipẹ yii ni Lalude ba ikọ AWIKONKO lalejo ni ọfiisi rẹ to wa nilu Ibadan, nibi to ti sọ oriṣiriṣi awọn nnkan tawọn ololufẹ rẹ ko mọ nipa rẹ. Ẹ ka ohun ti ỌLA EYITAYỌ ati YETUNDE ṢOYỌYE ba bọ lọdọ ogbontarigi oṣere tiata naa lẹkunrẹrẹ.
 
Oriṣiriṣi iwa idojuti lo n ṣẹlẹ lagboole tiata lasiko yii, to si n tabuku ba iṣẹ tiata. Pupọ awọn nnnkan wọnyii ni ko ri bẹẹ nigba tẹ ẹ bẹrẹ iṣẹ yii, nibo lo ti wọ wa?
Ori ko pe meji lọrun ẹni to ni i. Bi nnkan ba ṣe ori, ẹni to ni i naa lo fi n da laamu. Ẹni to ba ṣẹ, to si lu ofin, yatọ si pe o lu ofin ẹgbẹ ati ilu, to ba ti ṣẹ, ọrun ẹlẹṣẹ ni ẹṣẹ wa. Wọn ko le mu ẹni ti ko ṣẹ lati wa  jiya fun ẹlẹṣẹ, ko ṣe e ṣe. Gbogbo ẹni ta a ba ka nnkan ti ko dara mọ lọwọ ti ni tiẹ nibẹ tẹlẹ . Ika to ba si ṣẹ ni ọba n ge.
 
Wọn tiẹ lawọn aṣẹwo to pọ nidii iṣẹ yin lo ba iṣẹ  naa jẹ, ṣe loootọ ni?
O ya emi gan-an lẹnu pupọ, nitori pe ọpọ awọn nnkan ta a ko ri ri lo ti n ṣẹlẹ lagboole wa bayii. Idi iṣẹ tiata yii ni mo wa ti mo fi ra mọto, igba ti mo si ri i pe mọto naa n da mi laamu, mo ta a, mo si fi owo rẹ ra bulọọku, mo si fi kọ ile mi. Mi o si ti i ri ẹni fun mi ni mọto mi in latigba naa titi di akoko yii, bẹẹ si ni mi o kanju lati lọ ṣe nnkan mi in to yatọ si iṣẹ ti mo n ṣe lati ibẹrẹ pẹpẹ aye mi. Iyẹn di aye atunwa, nitori pe mo nigbagbọ pe nnkan ti Ọlọrun ba maa ṣe fun mi, ẹnu iṣẹ mi yii ni yoo ti ṣe e.
 
Awọn to n fi iṣẹ aṣẹwo jẹun laarin wa pọ rẹpẹtẹ, Ọlọrun lo si mọ wọn, ko sibi ti iṣe ko si, bo ṣe wa laarin wa naa lo wa nile ifowopamọ, lo wa nidii iṣẹ nọọsi; lo wa lọdọ awọn agbẹjọro ati bẹẹbẹẹ lọ kaakiri agbaye. Ṣugbọn ti wa ni wọn tete maa n ri, nitori pe gbogbo aye la n ṣere fun, idi ree to fi maa n kari aye bi igba wi pe ẹlomi-in ko huwa to ju bẹẹ lọ.
 
Ẹyin naa ti n kopa ninu ere oniṣẹju meji si mẹta ta a mọ si Skit, ṣe ka sọ pe nitori iṣẹ tiata ko ta mọ ni?
Nnkan teeyan ba mọ ọn ṣe naa ni wọn yoo fi lọ ọ. Owo gidi wa nidii ere oniṣẹju meji si mẹta yẹn lọ, owo naa si ju eyi ta a n gba nidii fiimu agbelewo. Idi ni pe ere iṣẹju perete yii sare tan kaakiri agbaye ju ti agbelewo lọ. Ọlọrun lo ni ipilẹ bo ṣe bẹrẹ, wọn pe mi si i, mo si ba wọn ṣe e. Awọn kan ti bẹrẹ ti wọn ti gbe e ju silẹ, awọn kan ṣi wa nidii ẹ, ṣugbọn igba to kan wa la a bẹrẹ yii.
 
Eewo lo lowo lori julọ ninu ere ori itage ati fiimu agbelewo lasiko ti oju ti la yii?
Ere ori itage ni, nitori pe a ti ṣiṣẹ sinu fiimu agbelewo ti wọn fẹẹ fi maa wa wa. Ti a ba lọ ṣere ori itage, awọn ero maa wa sibẹ rẹpẹtẹ lati ri wa.
 
 
Bawo gan an lẹ ṣe bẹrẹ iṣẹ tiata?
Mo n jo kaakiri nigba naa ni, ere ori-itage si ni mo le pe e. Mo n pawọn eeyan lẹrin-in kaakiri ode ariya nigba naa ni. Awọn ti wọn si kọkọ bẹrẹ ẹ ni Baba Ogunde, Onimọlẹ atawọn mi in. Awọn Baba Ogungbe ba wọn lẹnu ẹ ni. Irin tawọn yẹn rin naa lemi naa rin lati fi bẹrẹ. Fiimu ‘Ẹkun’ to jẹ ti Oloogbe Alade Aromirẹ ni mo kọkọ kopa ninu ẹ, iyẹn lọdun 1985, ko to di pe a bẹrẹ si i ya ‘Ajẹ n’Iya Mi’, ‘Akano Oni Kẹkẹ’, atawọn mi -in ko to de ori ‘Ogbori Ẹlẹmọṣọ’ to gbe mi jade.
 
Awọn elere kan lo wa lẹyin ọdọ wa ni Ṣogunlẹ l’Ekoo nigba yẹn, ti wọn maa n lu ilu ati orin. Ṣe ni ma a wa lọ duro lori oke lati maa wo nnkan ti wọn n ṣe. Lọjọ kan ni ẹni to maa n ba wọn lu aago ko wa, emi ni mo wa lọ ba wọn lu aago yii, latigba naa ni wọn ti fẹran mi, ti mo si di ọmọ ẹgbẹ wọn. Igba ti wọn fẹ lọ  ṣere opin ọdun wọn ni wọn ṣẹṣẹ wa a pe mi, ti wọn si mu mi dani lati lọ ọ ṣe ọmọ kekere ti wọn lu lẹgba wa sile lati ileewe.
 
Wọn bẹ mi titi lọjọ ti mo n sọ yii, igba ti mo tun bọ sẹyin itage yẹn, mo tun ṣi n sunkun, gbogbo bi wọn ṣe n bẹ mi ni mi o da wọn lohun. Wọn wa n beere lọwọ mi pe ṣe wọn lu mi ni, mo sọ pe ko sẹni to lu mi, ṣebi awọn ni wọn sọ pe ki n maa sunkun. Igba naa ni wọn ṣẹṣẹ wa n bẹ mi pe ki n dakẹ, ere ti pari. Emi naa wa a dakẹ, mi o le gbagbe ọjọ ti mo n sọ yii, nitori pe wọn tun n fi mi ṣe yẹyẹ, o si tun jẹ iyalẹnu fun wọn pe mo mọ nipa iṣẹ naa daadaa.
 
Bawo lẹ ṣe rin debi Ogbori Ẹlẹmọṣọ to fi di pe ẹyin ni wọn gbe ipa naa fun?
Eko ni mo wa nigba naa, ko si ọsẹ kan ki n ma ṣe ere ori itage ni National Theatre. Bi a ko ba ṣere tiwa, wọn a pe wa si iṣẹ ori itage nibẹ. Fiimu ‘Ogun Ahoyaya’ to jẹ ti Jide Kosọkọ la n ṣe lọdun 1989 naa lọhun, oriṣiriṣi oṣere ni wọn wa wo o, nitori pe wọn kan n gbọ iroyin ẹ ni. Fiimu yii la fi ṣe ifigagbaga fun ijọba ipinlẹ Eko lọdun 1987. Baba Ẹda ko da mi mọ nigba naa nitori pe emi ati wọn ko duro sọrọ ri. Awọn ẹgbọn mi bi i Ọnku Bello, Jide Kosọkọ, Aluwẹ atawọn mi in ni wọn wa nibẹ. Bello lo dari fiimu Ogbori Ẹlẹmọṣọ yii, mi o mọ nnkan to ṣẹlẹ to fi di pe wọn ko fẹẹ lọ Buọda Aṣafa, to ti n ṣe ipa Lalude naa tẹlẹ, eyi to mu ki wọn ronu kan mi. Awọn bi i Dentọ, Amos lo ti ko ipa yii ri, ṣugbọn wọn fẹ ẹni to tun le ṣe e daadaa ju ti wọn lọ. Ọga Bello lo sọ pe ki wọn lọ pe mi wa, Baba Aluwẹ si fẹran mi gidi gan-an. National Theatre ni Buọda Jide Kosọkọ, ti wa jiṣẹ fun mi pe wọn n pe mi lati wa a ṣe Ogbori Ẹlẹmọṣọ, ṣe ni mo laanu pe emi kẹ.
 
Wọn ni Buọda Aluwẹ sọ pe ki n tete de, nitori pe ọjọ keji, yẹn ni ayẹyẹ ọjọ ibi wọn bọ si, ati pe wọn fẹ ki n wa nibẹ ko to di pe wọn bẹrẹ ayẹyẹ ọjọ ibi naa. Lanlatẹ ni mo ti lọ ba wọn. Bi mo ṣe n debẹ ni wọn bẹrẹ ayẹyẹ naa, ti a si n ṣe faaji. Wọn ni idaniloju ninu mi pe ma a kopa naa daadaa ju bi wọn ṣe fẹ lọ.
 
Bawo lo ṣe ri lara yin nigba ti wọn gbe ipa naa fun  yin?
Mo ti ṣere oloogun ri, ṣugbọn mi o kopa Ẹlẹmọṣọ ri. Bi mo ṣe debẹ lọjọ yẹn, Baba Ẹda Onile-Ọla, n wo mi pe ṣe emi le ko ipa yẹn ṣa, nitori pe imura ọmọ ileewe ni mo mu lọ sibẹ. Nigba ti wọn tọka mi fun Baba Ẹda pe emi ni mo fẹẹ ṣe Ẹlẹmọṣọ ni wọn ti bẹrẹ si ni pọfọ. Mo rin baba-nla ẹrin lọjọ yẹn pe ki lo tun fa ọfọ ninu ọrọ to wa nilẹ yii. Mo fẹẹ pọfọ lọjọ yẹn ṣugbọn ẹrin lo tun n pa mi. Ọga Bello lo sọ fun wọn pe Fatai niyẹn, o maa ṣe e. Wọn wa ko wa wọnu yara kan pe ka pọfọ, mi o ṣa le pọfọ kankan, ẹrin ni mo kan n rin. Nigba ta a fẹẹ bẹrẹ ipa akọkọ ti mo maa ko ninu fiimu yii, aarin ọja la a ti ṣe e, wọn ko ti i roju mi ni gbogbo igba yẹn, ọrọ lasan la n sọ. Baba Ẹda pe mi sẹyin, wọn beere pe ọrọ kan ṣoṣo wo ni mo le sọ to le gbẹmi eeyan to pọ, mo sọ pe ‘iwọ’ nkọ? Wọn ni ki lo n jẹ bẹẹ, mo sọ pe ‘majele’ ni, wọn si ni ko buru. ‘Iwọ’ yẹn lemi ti gbe kalẹ nigba ti mo ṣi maa n kọ awọn itan arosọ (lines) mi silẹ pẹlu awọn ọfọ oriṣiriṣi.
 
Mo ti kọ ‘Iwọ’ yẹn silẹ ti pẹ, ti mi o mọ pe Ogbori Ẹlẹmọṣọ lo maa wa wulo fun, mo si ri i pe wọn gbadun ẹ. Nigba ta a maa lọ soju ija gan-an nigbẹyin fiimu yii, emi pẹlu Baba Ẹda ni. Gbogbo araalu lo tan sibẹ. Ibi ta a ti n ṣe idanrawo pe ka le mọ ba a ṣe maa ṣe e ni Aluwẹ ti sare wa, to si gbe mi soke nigba to ri ara ti mo da. Wọn ni ṣe maa ṣi ranti gbogbo awọn nnkan ti mo sọ yẹn, mo sọ pe ṣe bi a ko ti i bẹrẹ, idanrawo lasan ni, ki wọn maa woran pe maa ranti.
 
Nigba ta a pari, Baba Ẹda wa ba mi, wọn ni ṣe loootọ ni pe Eko ni mo ti wa, mo sọ pe bẹẹni. Bi a ṣe ya Ogbori Ẹlẹmọṣọ niyẹn.
 
 
Onsọtan, Onkọtan ni yin, nibo lẹ ti jogun ẹ, abi ẹ lọ ka a nileewe ni?
Mi o ka a nileewe rara o, mo kan mọ pe nnkan ti Ọlọrun ba fẹẹ fi ran eeyan, Ọlọrun naa lo maa ṣeto ẹ nirọrun.
 
Fiimu yin di meloo bayii?
Bi i marun-un si mẹfa ni gbogbo ẹ. Aarin Agbami ni mo kọkọ ṣe lọdun 1987 si 1988, awọn bi i Ogogo, Yinka Quadri, Lọla Idijẹ ni wọn wa ninu ẹ nigba naa. Lẹyin eyi ni mo ṣe ‘Akano Onikẹkẹ’, ti mo si lewaju ipa inu ẹ; Mo ṣe ‘Ẹru Were’; Mo ṣe ‘Jagun Ọkẹ’; Mo ṣe ‘Ibeji Meji’; Mo ṣe ‘Apo Iwe’.
 
Eewo ninu awọn fiimu yin yii lẹ ko le gbagbe bi ẹ ṣe poopọ nigba naa?
Ẹru Were yẹn ni. Bi mo ṣe kọ ṣe diẹ, nitori pe Lukuluku ṣi wa laye nigba naa. Emi ati Lukuluku jọ n lọ lọdun naa lọhun ni, mo kan sọ fun un pe mo fẹ kọ itan kan bayii, ‘were’ lo maa ṣe nibẹ. O beere iru itan naa lọwọ mi, mo si bẹrẹ si ni sọ fun un. Gbogbo asiko yii, mi o ti i kọ ọ silẹ, mi o si ti i mọ bo ṣe fẹẹ jẹ. O beere lọwọ mi pe ṣe mo ti kọ ọ silẹ, mo ni rara, o ni ṣe maa ranti, mo ni ko maa woran, wi pe mi o le gbagbe mọ bi mo ṣe n sọ ọ yẹn. Itan arokọ nipa imisi ni, to si ni itumọ gidi.
 
Awọn ọfọ yii, nibo ni wọn ti n wa?
Takada ati kalamu ni mo maa n mu lati kọ wọn silẹ, maa ṣẹṣẹ wa a gbe e sori lati mọ ọn. Kikọ silẹ yẹn ko le to ka gbe e sori, iyẹn gan-an niṣẹ. Mo ṣaa kan mọ pe nipa imisi atoke wa ni, bi mo ba ti mu iwe lati kọ ọ silẹ, o kan maa wa si mi lori ni, ma a si maa kọ silẹ.
 
Ṣe idile ifa lẹ ti jade ni, abi ki lo de ti ẹ fẹran ipa babalawo?
Awọn baba-nla wa ti wọn mọ nipa ẹ ko si laye nigba temi maa de ile aye. Igba ti mo dagba, ti mo gbọnju ni wọn ṣe n sọ fun mi pe baba-baba wọn kan n ṣe bakan naa. Mi o gbọnju ba iṣẹ naa nile rara, bi Ọlọrun ṣe n ṣiṣẹ ẹ lo yatọ.
 
Iṣẹ wo lẹ tun yan laayo yatọ si iṣẹ tiata?
Mi o ni iṣẹ mi in yatọ si tiata yii.
 
Ta ni ẹ le tọka ẹ gẹgẹ bi ọga yin nidii iṣẹ yii?
Oluwọle Concert Party ni mo kọkọ darapọ mọ, ọdun 1974, ni mo kuro lọdọ wọn, mo ṣẹṣẹ waa darapọ mọ Ademọla lọdun 1976.
 
Ki lawọn ipenija nigba yẹn?
Kin ni awa fẹẹ mọ to n jẹ ipenija, awa ko da nnkan to n jẹ ipenija mọ nigba ta a bẹrẹ, ere la kan n ṣe ni ti wa, igba ta a dagba, ta a mọ iyatọ laarin ọtun ati osi la ṣẹṣẹ n ri i pe o wa. Ipenija to ba a ba eeyan, ti ko ku, ko ti i ni ipenija, nitori pe ko si ẹni ti ipenija maa ba, ti ẹmi ẹ ba ṣi wa, ẹni naa ṣi ni nnkan n ṣe laye ni. Ti ipenija ba a ba eeyan gidi, ko ni i si laye mọ, iru awọn eeyan bẹẹ si ni ipenija jare wọn. Ṣugbọn awa ti jare ipenija niwọn igba ta a ṣi wa laye.
 
 
Njẹ ọjọ kan wa ti ẹ ronu lati fi iṣẹ tiata silẹ?
Mi o roo ri, nitori pe latigba ta a ti bẹrẹ, titi di akoko ta a n dagba si i yii, ko sibi ti mo de, ti wọn ko ti fẹran mi, koda, awọn agbalagba ti mo ba nidii oṣere naa fẹran mi gidi gan-an. Mi o wa le sọ pe boya mo ri nnkankan to fẹẹ fa mi sẹyin nibẹ.
 
Ki lawọn ipenija nidii ipa oloogun ti ẹ maa n ko?
O ti wa daadaa, mi o si le ka a tan. Lọdun kan, nigba ti mo ṣi wa l’Ekoo, awọn kan wa ba mi, wọn lawọn aparapọ babalawo ati oniṣegun, awọn awo ati ologboni, wọn mu lẹta wa pe ki n wa jẹjọ lọdọ wọn. Igba ti mo ka lẹta naa, ti mo ri nnkan to wa ninu ẹ, oju ẹni to mu lẹta naa wa ni mo ti fa a ya, ti mo si beere pe ki lo n daamu wọn, ṣe wọn mọ itumọ ipa ti mo n ko ninu sinima ṣa.  Mi o mọ nnkan to lọ sọ fawọn ẹgbẹ ẹ nigba to de ọdọ wọn.
 
Iyalẹnu lo jẹ nigba ti mo ri olori Apena wọn to wa ba mi, to si n dọbalẹ pe ki n ma binu, ọwọ wa lawọn dagba si, o lawọn baba yẹn ko mọ nnkankan nipa iwe tabi ẹkọ, o ni ti wọn ba kawe ni, wọn ko ni kọ lẹta naa wa. O ni wọn ko mọ pe awa la n ran wọn leti nnkan ti aye ti n gbagbe lati mọ pe awọn nnkan naa ṣi wa. Ẹni naa lo ṣaa lọ ba wọn sọrọ. Ọdun naa lawọn ẹgbẹ oniṣegun ibilẹ kan ti wọn pe ni  ANTREND wa lati ilu Oyinbo ati Naijiria lati fun mi ni awọọdu.
 
Nigba ta a ya Ogbori Ẹlẹmọṣọ yẹn, ọkunrin kan ko aṣọ oloogun meji wa pe ki n mu ẹyọ kan ti maa lo ninu ẹ, mo si mu, igba to ya lo pada wa, to si sọ pe ki n mu aṣọ naa foun pe oun fẹẹ lọ tun nnkan ṣe lara aṣọ naa, mo si mu aṣọ yii fun un, to si muu lọ. Bi mo ṣe wọ aṣọ naa ni mo ṣakiyesi pe otutu nla kan mu mi lasiko yẹn, ṣugbọn Alabukun ati ọti ni mo lo lati fi le otutu yẹn lọ. Aṣọ ti emi ati Baba Ẹda fi ja gbẹyin ninu fiimu naa ni mo n sọ.
 
Ko ti i ju ọdun marun-un lọ bayii ti ẹni to fun mi laṣọ yẹn waa ba mi, to si bẹrẹ si dọbalẹ to n bẹ mi pe ki n dariji oun. O ni ọkunrin ni mi, mo beere pe ki lo de?. O ṣẹṣẹ waa ṣalaye pe aṣọ yẹn toun gba nigba yẹn pe oun fẹ lọ tun ṣe, o ni irọ loun pa. O loun lọ yan an ni, iyẹn ni pe o lọ da oogun ti yoo pa mi si i ni. Mo wa rẹrin-in pe emi ko mọ pe ṣe lo lọ da oogun sinu aṣọ naa, iṣẹ tiata ni mo fi aṣọ naa ṣe. Igba yẹn ni mo waa ranti pe otutu mu mi gidi gan-an lọjọ yẹn, ọjọ naa ni mi o ba ku. Ṣugbọn ọsẹ keji, tẹni naa waa bẹ mi lo ku, ti mi o mọ pe iku ti wa lọrun rẹ.
 
Ẹni ti mo n sọ yii naa ti ko ipa Ẹlẹmọṣọ ri, o si lọ ran aṣọ naa lọna meji fun ara rẹ pe boya ti wọn ko ba ri ẹni to tun maa ṣe e mọ, wọn yoo pada pe oun, ṣugbọn emi ni wọn pada lo laimọ. 
 
Ajọṣepọ wo lo wa laarin ẹyin atawọn bi i Abija, Alapinni atawọn agbaagba mi-in ti wọn n ko ipa oloogun ninu ere.?
Ko ti i ju ọdun marundinlọgbọn ta a mọ ara wa, mi o mọ asiko ti onikaluku wọn bẹrẹ ere. Latigba ta a si ti mọra titi di akoko yii, mi o ro pe nnkan to buru wa laaarin wa.
 
Ajọṣepọ wo lo wa laaarin ẹyin ati Oloogbe Ajilẹyẹ?
Ere kan ṣoṣo ni mo ba wọn ṣe. Ere kan ṣoṣo naa si wa  dabi ogun ere. Abẹni Agbọn lorukọ ẹ. Emi o ki i lọ bi wọn ba n ṣe ipade. Ode faaji ni mo ti kuro laaarọ ọjọ naa, ti mo kan pinnu lati lọ wo nnkan ti wọn n ṣe. Bi mo ṣe wọle saaarin wọn, ni Baba Ajilẹyẹ, ṣe ‘Laila’, ti wọn si n tẹnumọ ọn, o n ya emi atawọn to wa nibẹ lẹnu pe ki lo n ṣẹlẹ. Mo waa sunmọ wọn lati ki wọn ku iṣẹ. Bi mo ṣe de iwaju wọn, wọn ni ‘Ọgbẹni Fatai, emi Yẹkinni ọmọ Ajilẹyẹ, mo tọrọ iru nnkan ti Ọlọrun fun un yin yii, ki Ọlọrun fun emi naa’. Wọn ni ki gbogbo awọn to ba n fẹ iru ẹ ko tọrọ lọwọ Ọlọrun, iyẹn awọn ti wọn jọ wa ninu ipade naa. Ṣe ni ori mi dide wu lọjọ yii.
 
Awọn to maa rahun, rahun, awọn to si maa tọrọ, tọrọ. Ọpọlọpọ awọn to wa nibẹ ni wọn ko mọ itumọ nnkan ti Baba Ajilẹyẹ sọ lọdun naa lọhun, ṣugbọn Baba Ajilẹyẹ to sọrọ naa lọdun yẹn ko mọ pe oun maa ku, ṣugbọn o mọ itumọ nnkan to sọ. Abẹni Agbọn yẹn nikan ni mo ba wọn ṣe. Ati ọba ati ijoye to wa nibẹ ni wọn dide duro fun mi lati patẹwọ, iyẹn nigba ti mo ṣere debi kan, to si ya wọn lẹnu. Ṣe ni wọn dide duro, ti wọn n pariwo nigba naa lai mọ pe wọn ti ba iṣẹ ti a n ya jẹ, inu wọn dun gidi gan-an ni.
 
 
Awọn kan nigbagbọ pe bi ẹ ko ba ti i da nnkan jẹ, imisi yẹn ki i wa. Ṣe loootọ ni?
Lọdun ta a fẹẹ ya Ogun Ahoyaya, Baba Aluwẹ wa ba mi, o ni ṣe mo ti mu igbo, mo sọ pe rara. O waa mu ọti kan to n mu lọwọ, o daa si sinu ife (cup) to gbe dani pe ki n mu, mo rẹrin-in gidi lọjọ yii. Ifigagbaga la si lọ ọ ṣe lọdun naa. Papi Luwẹ ni ki n ka lọ lati lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ lori itage. Awọn to wa lati ipinlẹ Ogun ni wọn n ṣere lọwọ nigba yẹn, I-Show-Pẹpẹ to wa ṣoju ipinlẹ Ogun lo wa lori itage, mo kan n wo wọn ni. Igba ti wọn ṣetan ni wọn pe mi nibi ti mo wa wi pe o ti kan mi. Ere to le ni, ẹni ti ko ba wo ere yẹn, ko le mọ itumọ nnkan ti mo n sọ. A ti wa a ṣe e l’Abẹokuta naa ri, ṣugbọn o ti pẹ.
 
Iha wo lawọn ọmọ yin kọ si ipa ti ẹ n ko yii?
Awọn ọmọ mi maa n fi ipa babalawo ati oloogun ti mo n ṣe ninu fiimu ṣere ninu ile. Iru ẹ ko le ṣe ko ma waye, yẹyẹ lawọn ọmọ mi maa n fi mi ṣe. Wọn a maa pọfọ ti wọn ko mọ lati fi mi ṣe yẹyẹ. Mo si maa n lo awọn ọmọ mi sinu fiimu ti mo ba fẹẹ ṣe lẹẹkọọkan, nitori pe iwe ti wọn n ka ko le fun wọn lanfaani lati lọ kaakiri.
 
Njẹ a tiẹ ri ọmọ yin kan to ya sidii iṣẹ yii?
Wọn ko ti i le ya sidii ẹ. Akọbi mi lobinrin, ilẹ Amẹrika lo wa lati ọdun 1996, oniṣegun oyinbo si ni. Ibẹ ti lo ti lọkọ, to si bimọ sibẹ. Ọmọ mi keji l’ọkunrin naa ṣẹṣẹ wọ fasiti Eko lọdun bi i meji sẹyin. Mo ṣi tun lawọn ọmọ to ṣi kere. Iṣẹ tiata wu wọn lati ṣe nigba ti wọn ri awọn igbesẹ temi naa gbe nidii ẹ, ṣugbọn wọn ko ti i ya sidi ẹ.
 
Njẹ ere oloogun tabi oniṣẹṣe ṣi wọpọ lasiko yii bi i tigba kan?
Bẹẹni, o ṣi wọpọ daadaa, ni nnkan bi ọsẹ meloo sẹyin, ere oniṣẹṣe ni mo lo ya l’Ado-Ekiti, ibẹ ni mo gba lọ si Ondo, ere oniṣẹṣe naa ni mo tun lọ ba wọn kopa ninu ẹ. Ko si eyi ti wọn pe mi si ninu ere oniṣẹṣe ati ti awujọ ti mi o ki i lọ, nitori pe ipa ti wọn ba mọ pe mo le ko ni wọn maa n fi mi si lati kopa, ma a si ṣe e to maa tẹ wọn lọrun.
 
Yatọ si ipa oloogun ti ẹ n kopa, awọn ipa wo lẹ tun ti ko?
Ko si ipa ti mi o ti i ko ri. Mo ti ṣe ọlọpaa ri, mo ti ṣe alakọwe ri. Aarin Agbami ti mo ṣe nigba naa lọhun, mi o ṣe babalawo ninu ẹ.
 
Njẹ ẹ tiẹ tun ṣi ni fiimu kan ti ẹ ti ṣe tẹlẹ, to jẹ pe ẹ tun n wo o lati tun pada gbe jade?
Bẹẹni, mo fẹẹ tun ‘Ẹru Were’ yẹn ṣe, nitori pe awọn eeyan ṣi n da mi laamu lori ẹ gidi. Awọn ti wọn ko ri i wo nigba naa ni wọn n fẹ ki n tun fiimu naa gbe e jade. Owo nla ni a maa fi ya a bayii, ki i ṣe owo kekere rara.
 
Bawo lo ṣe n ri lara yin  pe ijọba ko gbaruku ti iṣẹ tiata?
Ọgọrun-un ọdun tawọn oyinbo ti n ṣe fiimu agbelewo, awa ko ti i bẹrẹ. Nigba ti mo gbọ iye owo tawọn oṣere China ṣẹṣẹ fi pari fiimu kan ti wọn ya laipẹ yii, ẹnu ya mi, boya bi i miliọnu lọna ọọdunrun, iye owo wọn ni. Gbogbo oṣere ni wọn yoo fi owo yii ya fiimu kọọkan tabi meji-meji ninu owo naa. Ijọba wọn lọwọ si ni. Awa naa lo jẹ pe lẹkọọkan bi a ba pade awọn oloṣelu ni wọn maa ran wa lọwọ, ki i ṣe pe ijọba lo kan maa n pinnu lati ṣaanu wa. 
 
Njẹ ẹ ro pe awọn iwa ibajẹ to n ṣẹlẹ lagboole tiata le jẹ kijọba ronu lati maa ṣagbatẹru iṣẹ naa?
Nitori pe wọn ko ti i ka a kun ọrọ aje ni. Bi wọn ba ka iṣẹ tiata kun ọrọ aje ni, ijọba yoo dide lati ran wa lọwọ.
 
A ti n ri awọn to n dide lati ṣe bi i Lalude ninu iṣẹ tiata, njẹ wọn tiẹ le ṣe daadaa ju yin lọ bi?
Aidọgba ori ni ko jẹ ki wọn le ṣebi emi, wọn kan maa ṣe e niwọn ti agbara wọn ba ka ni.  Ṣe awọn nnkan ti mo ti ṣe sẹyin ni wọn fẹẹ sọ pe awọn fẹẹ le mi ba ni, abi eyi ti mo n ṣe lọwọ ni wọn fẹẹ di mi lọwọ ẹ wo?. Awọn naa maa gbiyanju lati ṣe nnkan ti agbara wọn ba gbe lati ṣe ni.
 
Idagbasoke wo lo ti deba iṣẹ tiata lasiko yii?
Idagbasoke wa daadaa, ṣugbọn idi ti idagbasoke naa ko fi jọ wa loju ni pe awọn ijọba ko da si. Idagbasoke to ni irọrun nisẹ tiata ti n ni. Ti wọn ba fẹẹ dibo nikan ni wọn maa n pe wa lati yọju sibẹ, ki wọn le mọ pe awọn sunmọ wa, bi anfaani naa ba si ti kọja, o tun di asiko ipolongo ibo miiran.
 
Ijọba maa n ṣeleri lati ran yin lọwọ, paapaa ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Ibikunle Amosun ṣeleri Theatre Village fun yin, njẹ a tiẹ maa n ri eyi to n mu ileri naa ṣe ninu wọn?
Ijọba Amosun mu ileri rẹ ṣẹ fun wa, ṣugbọn awọn ti wọn gbe e le lọwọ ni wọn ko jẹ ko ni idagbasoke kannkan. Amosun gbiyanju gidi fun wa, o si fun wa lowo gidi. Anfaani lati ri Amosun niru wa ko ni, bi mo ba ri i, yoo mọ ipinnu ti mo ni, nitori pe o da mi mọ. Gbogbo igba to n ṣe ipolongo idibo to kọja, emi ni mo maa n wa niwaju ẹ lati yinbọn soke. Mo ro pe o yẹ ki Amosun gan-an funra rẹ le maa ranti mi lẹẹkọọkan pẹlu ipa ti mo ko lasiko naa, ṣugbọn o ṣe ni laanu pe ironu wọn ki i debẹ bi wọn ba yo tan.
 
Kin ni ọjọ iwaju iṣẹ tiata pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii?
Aṣiri ọjọ iwaju iṣẹ tiata wa lọwọ awa oṣere asiko yii, nitori pe to ba jẹ pe bo ṣe ri lanaa la ṣe n ba a lọ lonii ni, ko sẹni to maa yo. Ni bayii, iṣẹ naa ti to o jẹ, o si tun ti n ṣẹku, to si n yo wa. To ba n lọ bẹẹ pẹlu idagbasoke pẹlu awọn to n wo wa, ọjọ iwaju ẹ maa tobi ju bayii lọ. 
 
 
Ko si iṣọkan laaarin ẹyin oṣere tiata mọ bi i tigba kan, ṣe ka ni ero to pọ nidii ẹ lo fa a?
Ki i ṣe ero to pọ nidii iṣẹ tiata lo ba iṣọkan rẹ jẹ. Ko si bi a ṣe le pọ to, iwa onikaluku maa yatọ ni. Iwa tonikaluku ni, lo n dide lati inu ẹ, to si n farahan. 
 
Bawo lo ṣe maa n ri lara yin bi ẹ ba ri ẹni ti ko to nnkan, to si n sọ pe oun ju bẹẹ lọ?
Aimọye ojo lo ti rọ, ti ilẹ ti fa mu. Ọpọ awọn to n huwa bẹẹ ni iku ti gbe ṣanlẹ, ti a ko ri mọ rara. Awọn to ku laye ni ki wọn maa ṣọra wọn, ki wọn si maa wo iru iku to pa awọn tiṣaaju ki wọn to tori bọ ọ.
 
Bi wọn ba n pariwo Lalude lọtun-losi bi ẹ ba n lọ lopopona, bawo lo ṣe maa n ri lara yin?
Ko rọrun rara, ṣugbọn o ti mọra. Aimọye ibi ti mo ti lọ to jẹ pe bi mo ba kuro nibẹ, awọn eeyan a tun gbe ọkada lati fi le mi, mo maa n yọ kuro laaarin wọn ni. 
 
Njẹ ẹyin naa da ile ẹkọ tiata silẹ lati maa kọ awọn eeyan ni ọfọ yin?
Mo ni awọn ti mo n kọ niṣẹ tiata lorukọ ẹgbẹ oṣere mi, mi o ni ileewe fun un.
 
Awọn wo lẹ le tọka si wi pe wọn ti ara yin jade nidii iṣẹ yii?
Ṣe awọn ọmọ ti mo kọ ni mo fẹẹ sọ ni, tabi awọn to n ji mi wo, mi o le ka wọn tan. Eeyan ko si gbọdọ sọ pe ẹnikan ti ara oun dide, nitori pe bo ti wu Ọlọrun lo n ṣọla rẹ. Olodumare lo n gbe eeyan dide, ki i ṣe eeyan. 
 
Oṣere tiata kan wa ti ẹ jọ ara yin, ṣe ọmọ ẹkọṣẹ yin ni tabi aburo yin?
A ko fi ibi kannkan tan mọ ara wa. Ẹni naa n ji mi wo ni. Iṣe mi lo si n wo dagba. 
 
Njẹ ẹ tiẹ ti figba kan ri tako ẹni naa wi pe o n ji i yin wo?
O digba tiru awọn eeyan bẹẹ ba ni afaani lati yọ ori mi kuro lọrun mi, ti wọn si gbe e si ori ara wọn ki n to o le sọrọ. Yatọ si eyi, oju ọrun to ẹyẹ fo lai fi apa kan ara wọn. Bi emi ṣe n ronu kọ ipa (lines) mi kọ lawọn ṣe n ronu kọ ti wọn. Mi o ti i dagba rara ti mo ti n kọ ọrọ (dialogues) silẹ funra mi. Igba ti mo n dagba yii lawọn ọrọ (dialogues) ti mo si ti kọ silẹ lati kekere yẹn ṣẹṣẹ wa n wulo fun mi. Awọn mi in lo jẹ pe mo ti gbagbe ohun (tone) ti mo fi kọ wọn silẹ, maa ṣẹṣẹ maa ronu si wọn ni ki n to o ranti, akatunka ni mo maa n fi wọn ṣe ko to o ye mi, ki n to le mọ ọn daadaa.
 
Ko le ye wọn bi mo ṣe gbe ẹbun mi kalẹ. Wọn ko le mọ bi mọ bi mo ṣe n ṣe agbẹkalẹ ẹbun mi lailai, nitori pe wọn ko le raaye lati faaye ẹ silẹ bẹẹ funra wọn lati ṣe. Mo ni ọrẹ kan, Abbey Lanre ni, oun maa n dari ere ni tiẹ ni, ile paanu la jọ n gbe l’Ebute Metta nipinlẹ Eko nigba naa. Lọjọ kan la fẹẹ dan ara wa wo, ayajọ ohun Ifẹ la mu lọjọ naa lati ha sori, ka si wo ẹni to maa kọkọ mọ ọn. Nigba to di ọjọ keji, a ni ka wa ka a funra wa, mo ni ko kọkọ ka tiẹ. Ila meji pere lo ka ninu ẹ lọjọ naa lọhun.
 
Nigba to kan emi, o ya a lẹnu wi pe mo ka gbogbo ẹ lati oke delẹ lai gbe e fo sira wọn. O tun pada lọ ọ ha a sori, fun oṣu kan le, ko mọ ọn, nitori pe o ju ara wọn lọ.
 
Iyatọ wo lo wa laaarin ẹni to ni ẹbun ati ẹni to lọ kọ ọ?
Bi eeyan ko ba ni ẹbun, to ba lọ kọ nnkan, ko le wulo fun un, nitori pe okun inu la fi n gbe tita. Ẹbun teeyan ba ni lo maa ran an lọwọ nigba to ba tun lọ kọ ọ siwaju si i, ko le ri i mulo.
 
 
Imura yin lori itage tabi fiimu agbelewo, ṣe iṣẹ ọwọ awọn aṣaraloge ni?
Funra mi ni mo n ṣe ara mi loge, nitori pe agbekalẹ mi ni, emi ni mọ nnkan ti mo fẹẹ ṣe. Bi mo ṣe n ṣe ara mi lẹṣọ yatọ si tawọn mi in, ṣugbọn awọn to n ṣe bẹẹ ti pọ bayii. Iṣoro ti wọn ni ni pe wọn ko ri ori mi gbe kuro lọrun mi lo n ṣe wọn, isọro kan ṣoṣo ti wọn si ni niyẹn. Mo maa n na owo gidi sori awọn aṣọ ti mo maa n lo ni. Mo ṣẹṣẹ ṣe aṣọ kan fun fiimu ‘Ọkunrin Ajẹ’ ti mo fẹẹ ya ni, bo tilẹ jẹ pe mi o ti i ri owo ti mo fẹẹ fi ya bayii, ṣugbọn mo n wo o pe nigba ti asiko ba maa to, aaye naa le ma yọ fun mi lati ṣe aṣọ naa. Mi o si ti i lo aṣọ naa ninu ere ri. 
 
Bawo lawọn aṣọ oloogun yin naa ṣe maa n gbe owo lori to?
Lasiko yii to jẹ pe owo ẹyọ ti wa a gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ. Aṣọ mi in maa n to ẹgbẹrun lọna aadọtatabi ju bẹẹ lọ. Ẹgbẹrun mẹẹdogun ni wọn n ta igo omi owo ẹyọ kan, bi eeyan ba si ṣe fẹ ki iṣẹ oun to, lo ṣe maa pọn ọn le to. Mo ṣi maa n gba aṣọ wọ, ṣugbọn mi o ki i ko aṣọ mi silẹ fun lilo, nitori pe aṣọ ti mo ba lo lẹẹkan, mi o ki i lo lẹẹkeji. Mo tun wa le pada dọgbọn si i tawọn eeyan ko fi ni mọ pe aṣọ kan naa ni.
 
Eelo lẹ kọkọ gba nigba ti wọn maa bẹrẹ si i fun un yin lowo ninu fiimu?
Ogbori Ẹlẹmọṣọ gan an ti mo ṣe nigba yẹn, ẹgbẹrun kan din lọgọrun-un (900) naira ni mo gba, iyẹn lọdun 1991. Ko pe ẹgbẹrun kan naira. Owo nla si ni nigba naa.
 
Bawo lẹ ṣe n ṣee pẹlu awọn ololufẹ yin obinrin?
Ibi to ba wu onikaluku ni ko ti ori ara rẹ bọ. Obinrin meloo ni mo fẹẹ ka. Awọn obinrin ta a jọ ja nigba Ogbori Ẹlẹmọṣọ pọ gidi gan an, akọ ni wọn ro pe mo n ṣe nigba naa, wọn ko mọ pe mo n ko ara mi nijanu ni. Oru ni wọn maa wọle tọ mi, ṣugbọn mi o ki i jẹ ki eyikeyi ninu wọn sun ti mi. A ṣe wọn n ba mi ja, mi o mọ. Lẹyin bi ogun ọdun la ṣẹṣẹ pari ija. Iṣẹ loogun iṣẹ lọrọ ẹni to ni ọjọ iwaju rere. 
 
Ọjọ wo ni inu yin dun ju?
Igba ti mo n ṣe ere ori-itage ni inu mi dun ju. Nigba tawọn eeyan ṣi maa n wa wo wa nigba naa ni. Ti n ba wa lori itage, ti mo n kopa lọwọ, ko si ẹyẹ to maa dun, nitori pe gbogbo rẹ maa pa lọlọ ni. To ba wa digba ti awọn ero iworan maa pariwo bayii, kekere kọ ni ariwo naa maa n jẹ. Idi ree ti mo fi fẹran ere ori itage ju fiimu agbelewo lọ. Ere ori itage ti wa gbowo lori ju fiimu agbelewo bayii. Eyi ti mo gba kọja yii, owo nla ni mo gba.
 
Ọjọ wo ni inu yin bajẹ ju?
Ere ori itage la lọ ṣe lọdun naa lọhun, bawọn tọọgi ṣe wa ka wa mọ niyẹn, ti wọn gun ori ẹni (mat) ta a tẹ silẹ lati fi ṣere. Awọn naa ko mọ pe a ko tọọgi ti wa dani. Ogbologbo tọọgi lo wa mọto to gbe wa lọ lọjọ yẹn, iyẹn lo ba wọn fa wahala lọjọ naa. Ori lo ko wa yọ lọjọ naa ti a fi sa lọ. To ba jẹ wọn ri wa mu ni, o ṣe e ṣe ki wọn pa wa, tabi ki wọn ṣe wa leṣe. 
 
Amọran wo lẹ fẹẹ gba awọn to n ronu lati ko iru ipa yin nidii iṣẹ yii lọjọ iwaju?
Igba yii, igba nni, igba naa. Igba yii la n lo, igba nni lo kọja, igba naa la ko mọ. Gbogbo ẹni to ba tori bọ ere ori itage tabi fiimu agbelewo, ti wọn si wa ninu ẹ lọwọlọwọ, ti ko ba ranti pe o yẹ koun ṣootọ ko to le ri ere gidi jẹ, inu irọ lo maa ku si. Bi oṣere kan ba si ku sinu irọ, ko le rọrun wọ. Pẹlu awọn ẹbun ti Ọlọrun fun oṣere tiata, bi a ba ronu pe ẹbun nla ni, a ko ni i huwa buruku, ṣugbọn sibẹ awọn alainitẹlọrun ninu wa ṣi n huwa buruku, oju wa si la maa fi ri iṣe wọn.
 
Nitori naa, wọn ni lati ṣọra wọn, ki wọn rọra sare lati ma ba a pade iku ojiji; ki wọn si ṣọ irin wọn lati ma ba a di ẹni ẹyin; ki wọn ṣọra lawọn ibi kan lati ma ba a ṣiwa hu. Ẹni to ṣi aye jẹ lo ṣiwa hu, Oodua ko fẹ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI