Ẹ gbọ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ṣàpèjúwe Olúfọlákẹ́, ìyàwó Gómìnà AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 3, 2021

Ẹ gbọ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ṣàpèjúwe Olúfọlákẹ́, ìyàwó Gómìnà AbdulRazaq

Lonii ni iyawo gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, iyẹn Arabinrin Olufọlakẹ AbdulRazaq n ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrinlelaadọta rẹ, ti gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye si ti n fi oriṣiriṣi atẹjiṣẹ ikinni ranṣẹ si i.
 
Ninu awọn ti wọn ko gbẹyin ninu fifi ẹmi imoore ati ikiini wọn han ni ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress, ẹka tipinlẹ naa Kwara, nibi ti wọn ti n ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi igi lẹyin ọgba tootọ fun ọkọ rẹ.
 
Alaaji Tajudeen Aro Fọlaranmi, akọwe ipolongo ẹgbẹ naa ninu atẹjade ikinni to fi ranṣẹ, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo tun ti ṣapejuwe Olufọlakẹ AbdulRazaq gẹgẹ bi awokọṣe awọn obinrin rere lawujọ, paapaa nipa iwa itẹriba ati ọyaya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI