Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́? Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kí wọ́n fi Ìgbòho sílẹ̀ n fẹ́ kó kú ni - Agbẹjọ́rò tú àṣírí tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 1, 2021

Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́? Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kí wọ́n fi Ìgbòho sílẹ̀ n fẹ́ kó kú ni - Agbẹjọ́rò tú àṣírí tuntun


Ọkan lara awọn agbẹjọro Oloye Sunday Adeyẹmọ ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho nilẹ Benin, 
Oluṣẹgun Falọla ti sọ pe bi ọkunrin naa ṣe wa lahamọ jẹ anfaani nla fun un, paapaa lati daabo bo o ni.

Agbẹjọro Falọla to jẹ Ọmọwe ninu ofin fikun ọrọ rẹ pe adehun ajọ ECOWAS gan an, eyi ti Naijiria ati Benin naa bu ọwọ lu nigba kan ri daabo bo Igboho.

Falọla ni ijọba Naijiria gan an ko fẹsun ọdaran kan Ọgbẹni Adeyẹmọ titi di akoko yii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
''Ofin orilẹ-ede Benin ko faaye gba ki eeyan wa ni atimọle ọlọpaa ju ọsẹ kan lọ.

"Awọn alaṣẹ ijọba Benin gbagbọ pe fifi Igboho silẹ lasiko ti awuyewuye ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ rẹ ni Naijiria ati Benin lewu fun aabo rẹ.

"Ijọba Benin ri i bi ẹni pe Igboho nilo aabo labẹ ofin titi di igba ti awuyewuye to tẹ le bi wọn ṣe mu un niluu Cotonou yoo fi lọ silẹ.

"Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, Igboho ko ṣẹ si ofin kankan lorilẹ-ede Benin. Koda, ko ti i lo to ọjọ kan ni Cotonou ti wọn fi mu un ni papakọ ofurufu ni ọna rẹ si orilẹ-ede Germany.

"Igba to ti i lo ni Benin kere debi wi pe ko le raaye lati gbero ati da wahala silẹ ni Benin.

"Awọn agbofinro mu un nitori ọrọ oṣelu lati orilẹ-ede Naijiria ni, ki i ṣe pe o ṣẹ si ofin nibi.

"Igboho si wa lahamọ lati jẹ ki atẹgun fẹ si ọrọ naa ati lati jẹ ki alaafia jọba laaarin Naijiria ati Benin.

"Ẹnikẹni to ba sọ pe ki wọn fun Igboho lominira bayii fẹ gba ẹmi rẹ ni, nitori wọn le ṣeku pa a."

Lori akoko ti igbẹjọ yoo tun waye nile ẹjọ, agbẹjọro Falola sọ pe awọn adajọ lo le sọ igba ti ẹjọ naa yoo tun gberasọ.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe ko ṣee ṣe ki Benin jọwọ Igboho fun Naijiria lori ẹsun pe o n pe fun iyapa ẹya Yoruba lara Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI