Ẹ wojú Sàlàkọ́ tó lu ọlọ́kadà pa l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 1, 2021

Ẹ wojú Sàlàkọ́ tó lu ọlọ́kadà pa l'Abẹ́òkúta


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ gendekunrin ẹni ogoji ọdun kan, Michael Salakọ, lori bo ṣe lu ọlọkada pa niluu Abẹokuta l'Ọjọru, Wẹside to kọja yii.

Ati pe kani ki i ṣe pe awọn eeyan tete mu Salakọ silẹ ni, boya ko ba ti na papa bora titi dasiko ta a pari iroyin yii, ki wọn ma si ti i ri.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, Salakọ ni wọn lo pe ọlọkada naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Abudu lati wa a gbe oun jade lọ sibi kan, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ṣugbọn ti wọn ni Abudu ko da a lohun.

Won ni Abudu ko ṣẹṣẹ maa gbe e Salakọ jade lọ sibi to ba n fẹ, ti wọn si ti wọnu ara wọn gidi.

Ọjọ naa ni wọn sọ pe Abudu loun ko le gbe Salakọ jade, nitori awọn idi kan ti ko sọ fun un.

AWIKONKO gbọ pe bi Salakọ ṣe ri Abudu lagbegbe Lafẹnwa lọjọ naa, lo lọ ba a lati beere idi ti ko fi wa gbe e, ṣugbọn ti wọn niyẹn ko da lohun


Nigba ti wọn ni Abudu ko da a lohun lo mu ko bẹrẹ si i gba a lẹṣẹ, ti ọrọ naa si bi Abudu ninu, eyi to jẹ ko gba a si ibinu.

Wọn nibi ti Abudu ti n lagidi ni Salakọ ti gba a gidi, to si ṣubu lulẹ, loju ẹsẹ lo ti daku.

Ere ni wọn lawọn to wa nibẹ kọkọ pe e, to mu ki wọn sare rọ omi lee lori boya yoo ji, ṣugbọn to ja si pabo.

Awọn to wa nibẹ ni wọn sare mu Salakọ silẹ, wi pe ko gbọdọ salọ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Wọn lawọn ọlọpaa ni wọn pada gbe oku Abudu lọ si mọṣuari fun ayẹwo.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI