Orí tún kó àwọn márùn-ún yọ lọ́wọ́ ikú òjijì l'Ọ́ṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 1, 2021

Orí tún kó àwọn márùn-ún yọ lọ́wọ́ ikú òjijì l'Ọ́ṣun


Awọn marun-un ni ori ti ko yọ bayii lọwọ iku ojiji loju ọna Ikirun si Ila-Odo, ipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti ti i ṣe Furaidee, ijẹta.
 
Wọn ni ṣe lawọn awakọ meji kan n ba ere asapajude lọ, ti awọn mejeeji si pada gba ara wọn lojiji. Ijamba naa la gbọ pe awọn to wa nibẹ faraba gidi, ṣugbọn ti ko sẹni to jade laye ninu wọn.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popona tijọba apapọ, FRSC ni wọn sare debẹ lati doola ẹmi awọn eeyan naa.
 
Agnes Ogungbemi to jẹ agbẹnusọ FRSC nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe mọto Mercedes Benz meji ọtọọtọ ni wọn gba ra wọn.
 
Benz akọkọ lo pe nọmba idanimọ rẹ ni FKJ351XX, nigba ti ekeji jẹ LRN980TD.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI