Méjì nínú àwọn ajínigbé to yawọ ìlú Ìwàjọwà pàdé ikú òjijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 1, 2021

Méjì nínú àwọn ajínigbé to yawọ ìlú Ìwàjọwà pàdé ikú òjijì


Awọn afurasi ajinigbe ti ko din ni meji ni wọn ti pade iku ojiji nijọba ibilẹ Iwajọwa, ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin tẹ wa lọwọ sọ pe asiko tawọn afurasi ajinigbe naa fẹẹ ji eeyan kan gbe lọrọ bẹyin yọ fun wọn niluu Iwere-Ile lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii.

Wọn ni nnkan bi aago mẹta lawọn ajinigbe naa yawọ agbegbe yii, lati ji awọn eeyan gbe. Bawọn eeyan si ṣe ri nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ yii ni wọn ti sare ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ eleto aabo Amọtẹkun.
 
Bi wọn ṣe ri awọn Amọtẹkun la gbọ pe wọn ti kọju ibọn si wọn, ti ọrọ naa si dabi fiimu agbelewo. Gbogbo awọn to wa lagbegbe yii ni wọn juba ehoro, ki aṣita ibọn ma baa ba wọn.
 
Wọn nigba tawọn afurasi ajinigbe naa ri i pe agbra awọn ko ba awọn Amọtẹkun yii, ni wọn ba gbiyanju lati na papa bora. Nibi ti wọn ti n salọ nibọn ti ba awọn meji, ti awọn yooku si salọ.

Adari Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọlayinka Ọlayanju fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o si lawọn ri nnkan ija oloro gba lọwọ wọn, ti wọn si ti ko wọn fawọn ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI