Wàhálà n bọ̀! Wòlíì Ayọ̀délé láwọn Taliban ń bọ̀ láti gbàkóso àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Nàìjíríà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 25, 2021

Wàhálà n bọ̀! Wòlíì Ayọ̀délé láwọn Taliban ń bọ̀ láti gbàkóso àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní Nàìjíríà


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii loootọ, afaimọ ni kawọn agbebọn kan ti wọn n pe ni Taliban ma pada gbakoso ijọba orilẹ-de Naijiria, paapaa pẹlu bi alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Babatunde Elijah Ayọdele ṣe sọ pe awọn agbebọn naa n gbaradi lati gbakoso awọn ipinlẹ kọọkan ni Naijiria.
 
Wọlii Ayọdele ninu asọtẹlẹ rẹ tuntun laipẹ yii ti sọ pe Ọlọrun ti fi han oun wi pe awọn agbebọn Taliban naa ti n gbaradi lati gbakoso awọn orilẹ-ede kọọkan nilẹ Afrika, eyi ti Naijiria naa wa lara wọn.
 
O ni kijọba Naijiria ma ṣe sun asunpara, bi ko ṣe pe ki wọn dide lati mọ ọna ti wọn yoo gba lati daabo bo awọn ẹnubode to wọ orilẹ-ede yii, ki awọn agbebọn naa ma baa ri aaye lati wọle wa.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii lawọn Taliban naa gbakoso ijọba orilẹ-ede Afghanistan lọwọ awọn alaṣẹ wọn.
 
Wolii Ayọdele tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe awọn eeyan naa ti n ko ara wọn jọ lọtun-lọtun lati gbakoso ilẹ Afrika, ati pe Naijiria jẹ ọkan pataki lara awọn orilẹ-ede ti wọn ṣetan lati gbakoso rẹ.

O ni ayafi bi ijọba Naijiria ba tẹle amọran, ti wọn si ṣe awọn ojuṣe to yẹ ki wọn ṣe, nikan ni aburu ko ni i ṣẹlẹ.

Siwaju sii lo kilọ fun ijọba Naijiria lati tete gbe igbesẹ lati daabo bo awọn ẹnubode, ki wọn si ṣiṣẹ takuntakun lori ọrọ eto aabo, pẹlu boun ṣe ri i wi pe awọn Taliban naa ṣe n gbakoso awọn ipinlẹ kọọkan ni Naijiria.

"Mo n ri awọn ẹgbẹ kan bi i Taliban ti wọn n dide nilẹ Afrika. Wọn n bọ lọna ara lati kọlu awọn orilẹ-ede kan nilẹ Afrika bii Burundi, Mali, Central Africa Republic, Benin Republic, Chad, Niger Republic, ati Naijiria.

"O maa lagbara gidi gan-an, nitori pe wọn ti n korajọ lati gbakoso awọn ipinlẹ kọọkan ni Naijiria bii Borno, Yobe, Adamawa, Nassarawa, Bauchi, Kaduna, Plateau, to fi mọ awọn agbegbe kan ni Benue ati Kogi.
 
"Mo ti kilọ tẹlẹ wi pe Boko Haram, ISWAP maa lọ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ agbebọn miran maa dide, o ti n fẹẹ ṣẹlẹ bayii, ayafi bi ijọba ba tete dide lati koju ẹ. Ninu ija lati koju awọn agbebọn wọnyi, ẹ jẹ ki wọn wa oju Ọlọrun. fun itọni.

"Taliban ko le pẹ ni Afghanistan, mo ri ijọba tuntun ni Afghanistan. Awọn ajọ agbaye gbọdọ ṣiṣẹ lori awọn ti wọn pe ara wọn ni Taliban yii, bo tilẹ jẹ pe fun bi ọdun mẹẹdogun si asiko yii ni orilẹ-ede naa ko fi ni ri ojutu ara wọn.
 
"Wọn maa ṣubu, ti wọn si ma maa wa awọn orilẹ-ede lati ku wọn, ṣugbọn ti wọn ko ni ri. Wọn maa pada kuna ni."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI