Akọ̀wé ìpolongo ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ́lẹ̀ fẹgbẹ́ sílẹ̀, ó ní kìí ṣẹgbẹ́ tó n mú ìlérí ṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 28, 2021

Akọ̀wé ìpolongo ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ́lẹ̀ fẹgbẹ́ sílẹ̀, ó ní kìí ṣẹgbẹ́ tó n mú ìlérí ṣẹ


Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Rivers tẹlẹri, Ogbanna Nwuke ti sọ pe oun ti kọwe fẹgbẹ naa silẹ, nitori pe wọn ko mu ileri wọn ṣẹ lati bi ọdun mẹfa sẹyin tawọn ti wa ninu ẹgbẹ ọhun.
 
Nwuke, ẹni to ti kọkọ ṣaaju kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi akọwe ipolongo ẹgbẹ naa laipẹ yii lo sọrọ naa lakooko to n bawọn akọroyin ipinlẹ naa sọrọ nilu Port Harcourt lọjọ Aje, Mọnde, ana.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ko si nnkan meji to mu koun fẹgbẹ naa silẹ, bi ko ṣe ti ẹlẹyamẹya ti bi wọn ṣe pa awọn ara agbegbe Etche toun ti wa ti, nibi ti ko ti si idagbasoke kankan.
 
O ni gbogbo ariwo toun n pa ati bawọn ṣe fọkan tan ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn ba a le mu idagbasoke ba ilu Etche lati bi ọdun mẹfa le diẹ sẹyin ni ko si ayipada kankan, to si loun ko le laju silẹ lati maa ṣe iru ẹgbẹ ti ko ni ọjọ iwaju rere fawọn eeyan mọ.
 
Nwuke sọ pe gbobo awọn ọrẹ oun ti wọn wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ati iṣakoso ijọba orilẹ-ede yii ti ẹgbẹ naa n dari rẹ ni wọn ko ri ti araalu Etche ro rara, eyi to sọ pe o n bi oun ninu, to mu koun pinnu lati fẹgbẹ silẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe Nwuke ko sọ boya inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lo n palẹmọ lọ, ṣugbọn to jẹ ko di mimọ pe oun ti gbaradi lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn to ba ṣetan lati mu idagbasoke ba ilu Etche.
 
Siwaju sii lo tun tẹnumọ ọn wi pe yoo jẹ aṣiṣe nla, boun ba tubọ duro sinu ẹgbẹ to ṣeleri ọjọ iwaju rere fawọn eeyan, ṣugbọn ti wọn ko mu ileri naa ṣẹ.
 
O tun jẹ ko di mimọ pe ko si eto irolagbara kankan fawọn araalu naa, bẹẹ si ni ko si ọmọ ilu naa ti wọn fun niṣẹ, depodepo wi pe wọn yoo mu idagbasoke ba ilu naa.
 
Bakan naa lo sọ pe inu oun dun boun ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ, dipo koun maa jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ ti ko ni ipinnu rere fawọn eeyan lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI