Àṣírí Akinọlá tó fipá já ìbálé ọmọ ọdún márùn-ún, ọmọ ìyàwó ẹ̀ tú l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, September 21, 2021

Àṣírí Akinọlá tó fipá já ìbálé ọmọ ọdún márùn-ún, ọmọ ìyàwó ẹ̀ tú l'Abẹ́òkúta


Olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa ni Eleweran nilu Abẹokuta ni baale ile, ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Ọladapọ Akinọla wa titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, nibi to ti n bẹbẹ fun oju aanu, lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọmọdebinrin, ọmọ ọdun marun-un to jẹ ọmọ iyawo ti Akinọla ṣẹṣẹ fẹ lo fipa ko ibasun fun, to si ṣe bẹẹ ja ibalẹ rẹ sọnu pẹlu agidi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to fi iroyin ọhun to wa leti sọ pe adugbo kan ti wọn pe ni Adewale Drive, eyi to wa lagbegbe Ṣokori nilu Abẹokuta niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aje, Mọnde, anaa, nigba ti wọn ni iya ọmọ naa lọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Adigbe leti.
 
AWIKONKO gbọ pe ki ṣe pe aṣiri yii deede tu sita, wọn ni asiko ti mama ọmọ yii n wẹ fun un lọwọ, lo ṣe akiyesi ẹjẹ labẹ rẹ, to si bẹrẹ sii beere lọwọ rẹ nipa nnkan to ṣẹlẹ.
 
Ọmọ naa lo sọ pe Akinọla lo gbe nnkan soun labẹ, ṣugbọn toun ko le sọrọ nigba naa, nitori pe ko ye oun si.
 
Loju ẹsẹ la gbọ pe obinrin yii ti pariwo sita, tawọn eeyan si sare lọ mu Akinọla nibi to wa. Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn wọ Akinọla lọ si teṣan ọlọpaa Adigbẹ, nibi ti wọn ti lọ ṣalaye ohun ti oju wọn ri.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun, nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awọn ti tare Akinọla lọ si ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ fifọmọ ṣoowo ẹru, ati lilo awọn ọmọde nilokulo lati tubọ fọrọ waa lẹnu wo.

Ajogun sọ pe pakopako ni Akinọla n wo nigba ti aṣiri rẹ tu sita, toun naa ko si sọ pe irọ ni wọn mọ oun. Eyi gan-an lo fi n gba awọn obi ati alagbatọ lamọran lati maa kiyesara iru ẹni ti wọn yoo maa fi awọn ọmọ wọn silẹ fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI