Àṣírí tu! EFCC bá òbítíbitì owó jìbìtì lọ́wọ́ Ladi, amúgbálẹ́gbẹ́ Saraki tẹ́lẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 3, 2021

Àṣírí tu! EFCC bá òbítíbitì owó jìbìtì lọ́wọ́ Ladi, amúgbálẹ́gbẹ́ Saraki tẹ́lẹ̀


Àṣírí owo biliọnu marun-un ataabọ le diẹ (₦5.3m) lo ti tu sọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, eyi ti wọn ni amugbalẹgbẹ Sẹnetọ Bukọla Saraki, Ladi Hassan gbe salọ.

Wọn ni asiko ti Sẹnetọ Bukọla Saraki fi wa nipo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kwara ni Ladi ko awọn owo naa jẹ.

AWIKONKO gbọ pe orúkọ ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Kaiser Strategic Services Ltd ni Ladi fi gbe owo naa jade lapo ijọba.

Nigba ti wọn gbe oriyin fun ajọ EFCC, ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Kwara Political Front, KPF, sọ pe iṣẹ nla gidi ni ajọ EFCC ṣe lati ri aṣiri ibi ti aduru owo naa wọle si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI