Àwọn agbébọn yawọ ibi ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọ́n pa ọmọ ẹgbẹ́ kan dànù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 28, 2021

Àwọn agbébọn yawọ ibi ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọ́n pa ọmọ ẹgbẹ́ kan dànù


Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta yii nigba ti wọn lawọn agbebọn kan yawọ ibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nijọba ibilẹ Nnewi North, ipinlẹ Anambra ti n ṣe ipade lọwọ, ti wọn si pa ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa sibẹ.

AWIKONKO gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Wọọdu Uruagu kẹta (Uruagu Ward 3) lo n ṣe ipade lọwọ, fun ti ipalẹmọ idibo gomina to n bọ lọna, lakooko tawọn agbebọ naa kọlu wọn pẹlu ibọn.
 
Wọn ni bi wọn ṣe n wọ ibudo ipade naa ni wọn ti n dabọn bolẹ, nibi ti ibọn ti ba ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Somadina Oforma.

Pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa nibi ipade ọhun la gbọ pe wọn farapa yannayanna lakooko ti wọn n ba ẹsẹ wọn sọrọ.
 
Ju gbogbo ẹ lọ, oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Andy Uba ti sọ pe ikọlu naa ko ṣẹyin ti ọrọ oṣelu, to si rawọ ẹbẹ si Gomina Willie Obiano lati gbe igbese ti yoo da ipaniyan ati wahala ojoojumọ nipinlẹ naa duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI