Ẹ dẹ́kun ìwa jìbìtì orí ayélujára - Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn pariwo síta fáwọn ọ̀dọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 1, 2021

Ẹ dẹ́kun ìwa jìbìtì orí ayélujára - Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn pariwo síta fáwọn ọ̀dọ́


Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti gba awọn ọdọ ati ọjẹwẹwẹ lamọran lati yẹra fun iwa to ba nii ṣe pẹlu jibiti ori ikanni ayelujara.
 
Lonii, Ojọru, Wẹside ni igbakeji gomina gbawọn ọdọ lamọran nibi aṣekagba  idanilẹkọọ ọlọsẹ meji ti wọn ṣe fawọn ọdọ nipa ẹrọ ayelujara, iyẹn Information Communication Technology (ICT), eyi to waye ni gbagede Ogun TechHub to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta.
 
Eto naa ti wọn ni awọn akẹkọọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ni wọn gbe e kalẹ fun ni ajọ Bureau of Information Technology, Ogun Techhub pẹlu ajọṣepọ Nigeria Computer Society (NCS), ẹka tipinlẹ Ogun ati ajọ aladani kan ti wọn pe ni Omọ Oye Foundation ṣagbatẹru ẹ.
 
Igbakeji gomina, Salakọ-Oyedele sọ pe ki gbogbo awọn akẹkọọ naa lo imọ ẹkọ ti wọn gba lati fi mu ara wọn dagbasoke, bẹẹ si ni ki wọn yago fun iwa jibiti ori ayelujara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI