Ìgbòho fárígá o! Ó l'agbẹjọ́rò toun san owó fún ti gbàbọ̀dì fóun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 7, 2021

Ìgbòho fárígá o! Ó l'agbẹjọ́rò toun san owó fún ti gbàbọ̀dì fóun


Olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ tọpọ awọn eeyan tun mọ si Igboho ti sọ pe agbẹjọro toun n san owo fun nilẹ Bẹnnẹ lati yọ oun kuro ninu ewu ti gbabọdi foun.
 
Igboho sọ pe ṣe ni Agbẹjọro naa n yẹyẹ oun nita gbangba, pẹlu boun ṣe n san owo gidi fun un to, to si loun ti ṣakiyesi wi pe o ti dalẹ oun.
 
Siwaju sii lo sọ pe oun ti ṣetan lati koju gbogbo iṣoro to ba ṣẹlẹ soun, nitori pe awọn nnkan toun ko lero lo ti n pada ṣẹlẹ bayii.
 
Igboho sọrọ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin kan lati ori foonu, to si ṣalaye awọn nnkan ti oju rẹ n ri lẹwọn, paapaa bo tun ṣe sọ pe agbẹjọro toun san owo fun yẹyẹ oun loju gbogbo aye.
 
Ninu ọrọ rẹ, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe:
 
"Ọkunrin ni mi, bi ko ba si ọkunrin nile mọ. Ibi to ka mi mọ ni o. Ọkunrin miliọnu kan ni mi bi ko ba si ọkunrin kankan nile mọ. Mo fi Ọlọrun to da ẹmi mi bura.

"Mi o kii ṣe ọkunrin to maa n bẹru ohunkohun. Mo maa n ṣebi dindinrin fun eeyan, ṣugbọn ti mo ba yiju pada, ko sẹni to le duro de mi. lọjọ ti mo yi ọrọ mọ wọn lọwọ nibi ti mo wa yii wi pe bi wọn ko ba pa mi, ki wọn ti mi mọle patapata, ki wọn ṣe ọkan ninu ẹ.

"Ninu ki ẹ yin gbogbo ibọn yin, ki ẹ pa mi sibi ti ẹ de mi mọ yii, tabi ki ẹ gbe mi kuro nibi, ẹ gbọdọ ṣekan. Mo duro tan lọjọ naa fun wọn, nitori wọn mọ ohun ti mo le ṣe.

"Mo n ṣe bi ọdẹ fun wọn, mo n sunkun bi dindinrin fun wọn, ti mo ba pada yiju pada si wọn, agbara wọn ko le ka mi mọ. Wọn n fi eeyan sẹwọn yii ko nitumọ si mi, ere itage lasan ni mo ka a si. Irin ti Sunday yoo rin laye ti wa lara rẹ pẹlu oun ati Ọlọrun rẹ.

"Bi mo ba ranti ọrọ Baba Muhydeen Bello, ara mi maa n balẹ ni, lọjọ ti baba naa n ba mi ṣile, ti awọn kan n ṣe garagara. Awọn Sẹnetọ, gomina lo wa nibẹ. Baba beere lọwọ wọn pe nitori taani wọn ṣe wa, wọn dahun pe nitori Sunday Igboho ni. Baba sọ pe o tan, nitori pe wọn n rii lo ni.

"O ni agbara to n lo nibo lo wa, gbogbo wọn woju ara wọn, o si ni ara rẹ ni Ọlọrun fi si. Baba ni Sunday maa n ṣe bi ọmọ kekere, ti ko sẹni ti ko le dọbalẹ fun, ṣugbọn wọn ko le ri ibi ti Ọlọrun fi agbara rẹ si lara rẹ.

"Wọn beere lọwọ mama ni pe ṣe ajẹ ni, mama mi sọ pe awọn kii ṣe ajẹ. Mo ti gba fun Ọlọrun nibi ti mo wa yii, mi o bẹru ẹnikankan mọ, lẹyin Ọlọrun to ni mi, gbogbo ohun ti wọn ba ri ni ki wọn fi da lara.

"Bi wọn ba gbe mi de iwaju adajọ yẹn, maa sọ fun un pe mi o bẹru ẹ, bi ko ṣe pe Ọlọrun to ni mi ni mo bẹru. Bi wọn ba fẹ gbe mi lọ Naijiria, ki wọn maa gbe mi lọ. Naijiria ti wọn n gbe mi lọ, ayafi ti ko ba si Ọlọrun nibẹ. Ti Ọlọrun ba ṣi n bẹ ni Naijiria, ki wọn gbe mi lọ, ko si nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ.

"Ṣebi Kanu wa nibẹ, ija ti mo n ja naa ni Kanu n ja. Gbogbo awọn nnkan yẹn, a fi n dẹru ba ara wa ni. mo ṣetan lati tẹle wọn lọ Naijiria, ayafi bi ko ba si Ọlọrun ni Naijiria lo ku. To ba jẹ Ọlọrun n bẹ nibẹ, ki wọn maa gbe mi lọ, ko si nnkan ti yoo ṣẹlẹ.

"O ti n lọ si bi oṣu meji ti mo ti wa nibi, ko wọn ko yọju si mi nibi lati sọ pe ẹni ti mo n gbẹjọ ro fun ree. Mo ni awọn agbaagba agbẹjọro ni Naijiria ti mo n dari wọn, ti wọn maa wa ba mi ninu ile mi. 

"Mo mọ iye agbẹjọro ti wọn lo n gbẹjọro fun mi n'Ibadan, mejilelogoji ni wọn, agbalagba agbẹjọro ni wọn, ti mi o tii fun wọn lowo kankan, bẹẹ si ni mo n bori ijọba apapọ. Nigba to jẹ pe Ọlọrun lo n ṣiṣẹ rẹ. Gbogbo awọn ti wọn si jẹ baba mi ni ko dakẹ adura, ti ọlọrun si n gbọ adura yẹn.
 
"Kii ṣe nipa agbara ijọba Bẹnnẹ ni mo fi wa nibi, ṣugbọn bi ko ṣe pe Ọlọrun fẹ ki n wa nibi ni. Mo si nigbagbọ pe Ọlọrun naa ko ni pẹ ẹ tu mi silẹ lẹwọn yii. Koda bi gbogbo awọn agbẹjọro ba sọ pe awọn ko ṣe mọ.
 
"Baba mi lagbara gidi nigba to wa laye, ṣugbọn o pada ku ni. Baba ati mama mi ko lowo lọwọ nigba naa, ṣugbọn ẹ wo emi ọmọ wọn lonii, mo lowo lọwọ."

 


 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI