Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe ko si nnkan toun fẹẹ maa duro ṣe lorilẹ-ede Naijiria lakooko yii mọ, to si loun ko tun ni pada wọlu, ayafi bi wọn ba fi Sunday Adeyẹmọ ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho silẹ lọgba ẹwọn to wa.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun yii ni awọn ọlọpaa agbaye, iyẹn Inter Pol tẹ Igboho nilẹ Bẹnnẹ lakooko to fẹ maa lọ si si orilẹ-ede Germany, nibi ti awọn ọmọ rẹ wa.
Latigba naa si lawọn eeyan, awọn agbẹjọro ti n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ọkunrin naa jade lahamọ orilẹ-ede Bẹnnẹ ti wọn fi pamọ si.
Nigba to n sọrọ lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Maxwell Adelẹyẹ, Ọjọgbọn Akintoye, sọ pe igbesẹ ṣi n lọ lori ọna lati gba Sunday Igboho silẹ, ati pe ko si ọna bo ṣe le pada wọ Naijiria lai jẹ pe wọn yọọ kuro lẹwọn to wa nilẹ Bẹnnẹ.
Akitoye sọ pe;
"O digba ti wọn ba fi Igboho silẹ ki n to le pada wọ Naijiria. Emi pẹlu awọn agba Yoruba kan ṣi n ṣiṣẹ lati ṣe iranlọwọ to ba yẹ lati rii pe wọn ko ṣe nnkan ti ko ba ofin mu fun Sunday Igboho.
"Bi mo ṣe pinnu lati maa gbe nibi, ko tunmọ si wi pe mo n bẹru ijọba Naijiria. Mi o ṣe ẹṣẹ kankan to le mu ki n salọ kuro ni Naijiria, gẹgẹ bawọn kan ṣe n gba a lero.
"Ẹtọ wa la n ja fun. Awa ọmọ Yoruba ko le tẹsiwaju lati maa ṣe ẹru mọ. A maa ja ijọba Naijiria laya pẹlu ipinnu wa. Ṣugbọn a ko ni jẹ ki wọn mọ ohun ti n pinnu rẹ labẹlẹ. Ọna to gbọgbọn ni. Awọn nnkan ti a ni la maa lo lati gba ohun ti a fẹ.
"Ọmọ wa ni Sunday Igboho, ti a si maa gbaruku ti i pẹlu eemi ikẹhin wa. Ko yẹ ko wa lahamọ nitori to n ja fun ominira awọn ọmọ Yoruba. mo fi daa yin loju pe awa la maa leke lati rii pe o jade, ṣugbọn mi o ni sọ ohun ti yoo tẹlẹ."
No comments:
Post a Comment