Sàlá, ìyàwó Bàba Sàlá náà ti jáde láyé o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, September 16, 2021

Sàlá, ìyàwó Bàba Sàlá náà ti jáde láyé o


Wẹre niroyin ibanujẹ naa tun wọ agbo awọn oṣere tiata ilẹ Naijiria wi pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, Arabinrin Bọlanle Adejumọ ti jade laye, iyẹn lana, Ọjọru, Wẹside.
 
Bọlanle Adejumọ, to jẹ iyawo ogbontarigi agba oṣere oṣere adẹrinpoṣonu nni to jade laye lọdun diẹ sẹyin, Oloogbe Moses Adejumọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Baba Sala la gbọ pe o jade laye lẹni ọdun mejidinlọgọrin.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ kulẹkulẹ aṣiri iku to pa Arabinrin Bọlanle, ṣugbọn ti wọn ni o ti ṣe diẹ to ti wa lori idubulẹ aisan. Awọn kan tiẹ sọ pe aisan ọjọ ogbo lo kọluu.

Ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Adejumọ Bọisala Emmanuel lo firoyin naa sita fawọn eeyan wi pe mama oun ti jade laye.
 
Bọisala ninu alaye to ṣe sọ pe mama oun bẹrẹ iṣẹ tiata alawada pẹlu baba oun ninu ẹgbẹ Alawada Comedy Group, to si ni mama oun lo kọkọ ko ipa Sala fun ọdun mẹẹdogun gbako, ko to di pe iya kekere wọle de lati tẹsiwaju ipa naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI