Ayé ò! Wọ́n pa Ṣọ́jà danù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún jí ìyá àtàwọn ọmọ rẹ̀ gbé lọ́jọ́ kan ṣọṣọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 15, 2021

Ayé ò! Wọ́n pa Ṣọ́jà danù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún jí ìyá àtàwọn ọmọ rẹ̀ gbé lọ́jọ́ kan ṣọṣọ


Awọn agbebọn tun ti pa ṣọja kan danu nipinlẹ Kaduna, ninu ikọlu tuntun to waye laipẹ yii. Bẹẹ ni wọn tun ji iyaale ile ati awọn ọmọ rẹ gbe salọ.


Ile ọkan lara awọn oṣiṣẹ fasiti ipinlẹ Kaduna, iyẹn Kaduna State University (KASU), Ọmọwe Ahmed Buba, to wa lagbegbe Milgoma, niwaju Ahmadu Bello University Teaching Hospital, Shika Zaria ni wọn lawọn agbebọn naa ti ṣọṣẹ.
 
Eeyan mẹrin ọtọọtọ ni wọn jigbe ni nnkan bi aago mẹsan alẹ ọjọ Aje, Mọnde ijẹta.
 
Ana la gbọ pe wọn koju awọn agbebọn naa lagbegbe Kasuwar Da’a to wa loju ọna Birnin Gwari.
 
Okekechukwu Ebuka lorukọ ṣọja ta a gbọ pe wọn pa danu.

AWIKONKO gbọ pe awọn agbebọn ti ko din ni ọgbọn, ni wọn ya wọ agbegbe naa pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro loriṣiriṣi.

Bi wọn ṣe wọle la gbọ pe awọn ara agbegbe yii ti ranṣẹ sawọn ọlọsẹ, awọn ṣọja ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo kan fun iranlọwọ, ti wọn si ni gbogbo wọn ni wọn ko fi ọrọ ọhun falẹ, ti wọn fi lọ koju awọn agbebọn yii.
 
Nibi ti wọn ti n fibọn fagba han ara wọn la gbọ pe ọkan lara awọn ṣọja naa ti sọda sọrun alakeji.
 
Enikan to ṣalaye ohun to ṣẹlẹ yii fawọn akọroyin sọ pe mẹfa ninu awọn ọmọ ti wọn jigbe lawọn oṣiṣẹ ologun naa gba silẹ pada nijọba ibilẹ Kasuwan Da’a.
 
Wọn ni obinrin kan, Rabi Isya ati awọn ọmọ rẹ, Sulaiman Isya, Amina Isiya ati Mus’ab Isya ni wọn jigbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI