APGA, PDP pàdánù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sọ́wọ́ APC l'Abùjá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 31, 2021

APGA, PDP pàdánù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sọ́wọ́ APC l'Abùjá


Ko din ni ẹgbẹrun mẹrin ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ati All Progressive Grand Alliance, APGA ti wọn ti yawọ inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC bayii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ẹgbẹ oṣelu APC ti ẹkun Kwali, to wa nilu Abuja la gbọ pe awọn eeyan naa wọ

Lonii ni minisita f'ọrọ ipinlẹ ni FCT, Ọmọwe Ramatu Aliyu, lo sọ eyi di mimọ lonii, ọjọ Aiku, Sannde lati ọwọ amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Austine Elemue.

Nigba to n gba awọn yo ṣẹṣẹ darapọ naa wọle sinu ẹgbẹ APC, Aliyu fọkan wọn balẹ lori otitọ ati awijare, to si n pe awọn ti ko tii darapọ lati tete maa bọ ki asiko too lọ.

O wa gba wọn lamọran lati lo agbara ti wọn ni ninu oṣelu lati jẹ ki APC jawe olubori lọdun 2022 ati awọn ọdun ti yoo tẹle e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI