Ẹ fura o! Ayédèrú owó làwọn eléyìí fi n lu àwọn aráàlú ní jìbìtì kọ́wọ́ tóo tẹ̀ wọ́n - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 3, 2021

Ẹ fura o! Ayédèrú owó làwọn eléyìí fi n lu àwọn aráàlú ní jìbìtì kọ́wọ́ tóo tẹ̀ wọ́n


Boroboro bayii lawọn gendekunrin mẹta ti ẹ n woju wọn yii n ka lakooko tọwọ ọlọpaa tẹ wọn, ti wọn si tun jẹwọ pe o ti pẹ tawọn ti wa nidii iṣẹ jibiti naa.

Ayederu owo naira la gbọ pe wọn n ta lati maa fi lu awọn araalu ti ko nnkan mọ ni jibiti.
 
Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ṣoṣo ni tolohun gan-an lo jẹ ki aṣiri wọn pada tu sita.
 
Anas Lawal, Abdulaziz Wada ati Tasi’u Umar lorukọ awọn mẹtẹẹta ti wọn sọ pe ọwọ tẹ naa loju ọna Funtua si Kaduna, ipinlẹ Kaduna.

Ninu ọrọ ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Gambo Isah sọ lo ti jẹ ko di mimọ pe Lawal lọwọ palaba rẹ kọkọ segi, ko to ṣatọna bọwọ ṣe tẹ awọn meji yooku.
 
O ni ọga wọn, Usman Gombe to n ko ayederu owo naira naa fun wọn lati maa ta a ti na papa bora, ati pe awọn ṣi n wa a lati mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI