Ẹ wojú Garuba yìí dáadáa, ògbólògbó ni nínú ká jí ewúrẹ́ gbé ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 17, 2021

Ẹ wojú Garuba yìí dáadáa, ògbólògbó ni nínú ká jí ewúrẹ́ gbé ní Kwara


Ọrọ Yoruba kan to sọ pe 'ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ni t'olohun' lo lọ gẹlẹ ni ibamu pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Garuba Ashin nijọba ibilẹ Kaiama, ipinlẹ Kwara l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii.
 
Nibi ti wọn sọ pe Garuba ti n le ewurẹ naa lati mu lọwọ palaba rẹ ti segi, ti ko si le gbagbe iya to jẹ lọjọ naa nigbesi aye rẹ.
 
Gẹgẹ bi awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti ṣe sọ, wọn ni kii ṣe akọkọ ree ti Garuba yoo maa ji ewruẹ, adiẹ atawọn nnkan ọsin miran gbe lagbegbe Iwala to wa nijọba ibilẹ Kaiama, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ pe oun ni.

Lẹnu ọjọ mẹta yii la gbọ pe bi awọn nnkan ọsin, paapaa ewruẹ ṣe n sọnu lagbegbe naa mu ifura dani gidi, eyi to jẹ ki awọn eeyan lọ fọrọ naa to awọn eleto aabo ara ẹni laabo ilu, iyẹn Sifu Difẹnsi leti, ti wọn lawọn yẹn kọ wọn ni ohun ti wọn yoo ṣe lati mọ iru anjọọnu to n ṣiṣẹ naa mu.
 
Wọn ni latigba yii lawọn eeyan ti n dọdẹ rẹ, ti wọn si lawọn eeyan ko fi ọrọ ọhun ṣere rara.
 
A gbọ pe bi adugbo naa ṣe da paro lọjọ ti a n sọ yii, ni Garuba tun wọbẹ lati ṣe bo ṣe maa n ṣe, lai mọ pe awọn eeyan n ṣọ oun. Wọn lawọn to rii lakooko to n le ewurẹ naa mu farabalẹ fun un gidi, ti wọn si ṣebi ẹni pe awọn ko rii.

Bo ṣe mu ewurẹ yii tan, lo n gbe e lọ, ko to di pe wọn daa duro lati beere ibi to ti ri ewurẹ to gbe kọrun. Wọn ni ṣe ni ọrọ di womi-n-wo ẹ nigba ti aṣiri rẹ tu, paapaa ti ko le sọ pato bi ewurẹ naa ṣe de ọwọ rẹ.

Eyi lo jẹ ki wọn ranṣẹ sawọn Sifu Difẹnsi lati wa wo ẹni ti pampẹ wọn mu.
 
Babawale Zaid Afọlabi, nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ f'AWIKONKO sọ pe ẹni kan to n jẹ Hossan Abubakar lo ni ewurẹ ti Garuba jigbe, to si ni o ti wa ni olu ileeṣẹ awọn to wa ni Ilọrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI