Ìdánwò ìgbéga bẹ̀rẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ Kwara lónìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 19, 2021

Ìdánwò ìgbéga bẹ̀rẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ Kwara lónìí


Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa ni idanwo igbega si ipele tuntun fun ti ọdun 2021 ti a wa yii bẹrẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Kwara.

Alaga ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba, iyẹn Civil Service Commission, Hajia Habeebat Anikẹ Yusuf lo sọ eyi di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ana.

Hajia Habeebat nigba to n fidi iroyin naa mulẹ sọ pe awọn oṣiṣẹ ti wọn wa ni ipele keje ati ipele kẹjọ ni yoo ṣe idanwo naa ti yoo bẹrẹ laaarin agogo mejila si meji ọsan, to si tun jẹ ko di mimọ pe Staff Development College, to wa niluu Ilọrin ni idanwo naa yoo ti waye.

Bakan naa lo sọ pe kii ṣe ọjọ kan ṣoṣo ni idanwo yii yoo fi waye, bi ko ṣe pe lati oni, ọjọ kọkandinlogun si ọjọ Aje, Mọnde to n bọ, iyẹn ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii ni yoo fi waye.

Siwaju sii lo ṣe ikilọo fun gbogbo awọn akopa lati rii daju pe wọn peju pẹsẹ sibi idanwo naa, nitori pe awọn ko ni tun un ṣe fun ẹnikẹni ti ko ba ti yọju lasiko to yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI