Lonii, ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 ni idije ere bọọlu ti wọn pe ni Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation Charity Cup, tọdun 2021 bẹrẹ nilu Ifọ, ipinlẹ Ogun, nibi ti awọn akopa ti bẹrẹ sii mọ iwọn ti wọn gbe.
Ẹgbẹ agbabọọlu ti ko din ni mẹrinlelogun la gbọ pe wọn fẹẹ figagbaga lati mọ ẹni ti yoo jawe olubori, lara wọn ni ẹgbẹ agbabọọlu Ṣẹgun Ọdẹgbami Academy, Ewekoro United atawọn mi in.
Nibi ti wọn ti ṣe eto bi awọn ẹgbẹ agbọọlu naa yoo ṣe wa ni pele-ipele la gbọ pe wọn ti pin wọn sọna mẹfa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin-mẹrin lati koju ara wọn nibi ipele akọkọ, iyẹn Group Stage.
Lara awọn to wa nibẹ ni oludasilẹ, Oloye Olumide Aderinokun, awọn alẹnulọrọ nidi ere idaraya nipinlẹ Ogun, awọn aṣoju ẹgbẹ agbabọọlu, to fi mọ awọn ọjọgbọn nidi iṣẹ rẹfirii.
Awọn to wa ni ipele kin-in-ni ti Group A ni Onyx FC, Daleko FC, Patoko All Stars ati Abatan FC; Awọn to wa Group B ni Santos FC, Bavis FA, Concord FA ati Ilepa United FC.
Ẹgbẹ agbabọọlu Ewekoro United, Chosen Generation FC, Ajax FC ati Alaja FC lo wa ni Group C, nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Ṣẹgun Ọdegbami Academy, Ultimate FC, Eruku FC ati All Stars FC wa ni Group D; ti ẹgbẹ agbabọọlu Onikoko FC, Evolution FC, Dynamite FC ati Grassroot FA wa ni Group E ni ti wọn.
Awọn gbẹyin ni Group F ni Isheri Olofin FC, Amazing FC, Olofin FC ati S.P Football Academy.
Aago mẹta, ọsan oni ni ẹgbẹ agbabọọlu Onyx FC ati Dalekọ FC fagba han ara wọn ni papa iṣere ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ti N.U.D to wa nilu Ifọ.
Nigba to n sọrọ, Oloye Olumide Aderinokun sọ pe lojuna lati jẹ ki awọn ọdọ orilẹ-ede yii, paapaa nipinlẹ Ogun mọ pataki ere idaraya lo jẹ koun gbe idije naa kalẹ, ati pe ko sẹni to kopa nibẹ, ti ko nii pada sile pẹlu ẹbun.
Aderinokun sọ pe titi lai ni idije naa yoo maa waye, ti kii sii ṣe pe lẹyin eyi, ko tun ni pada waye mọ. O jẹ ko di mimọ pe ipinnu oun ni lati gbe eto ere idaraya larugẹ.
No comments:
Post a Comment