Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, lopin ọsẹ to kọja yii ti bu ẹnu atẹ lu Pasitọ tunde Bakare to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Citadel Global Community lori bo ṣe loun fẹẹ jade du ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023, to si ni iṣẹ Ọlọrun to yan laayo ni ko gbajumọ, dipo ipo oṣelu to n le kaakiri.
Wolii Ayọdele nigba to n sọrọ sọ pe oun to da oun loju ni pe Pasitọ Tunde Bakare ko le gbe apoti ibo ninu ṣọọṣi rẹ to da silẹ, ko si wọle.
Bakan naa ni Wolii Ayọdele ti asọtẹlẹ rẹ ti wa si imuṣẹ lọpọ igba tun tẹsiwaju pe ṣe lo yẹ ki Pasitọ Bakare kọju mọ iṣẹ ti Ọlọrun gbe lee lọwọ, ko si yee ṣi oore ọfẹ Ọlọrun to wa lori rẹ lo.
Bẹ o ba gbagbe, Pasitọ Bakare ti jade du ipo igbakeji aarẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣugbọn ti wọn jọ padanu lọdun meloo kan sẹyin. Ṣugbọn laipẹ yii ni Pasitọ Bakare sọ pe oun ti ṣetan lati jade du ipo naa, iyẹn bi Ọlọrun ati awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ba sọ pe o ti ya.
Nibi to ti bawọn akọroyin sọrọ lẹyin abẹwo to ṣe lọ sile agbara orilẹ-ede yii to wa ni Aso Rock niluu ABuja lọsẹ to kọja yii ni Pasitọ Bakare tun ti ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to n tun ilu ṣe.
Wolii Ayọdele ninu atẹjade to gbe sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ, lo ti gba Pasitọ Bakare lamọran lati maa lo owo rẹ fi ṣaanu awọn to ku diẹ kaato fun ninu ijọ rẹ, dipo ko maa na ninakuna, eyi ti ko ni ere kankan lọdọ Ọlọrun.
"Tunde Bakare ti n ṣi oore ọfẹ Ọlọrun lori aye ati iṣẹ iranṣẹ rẹ lo. Ala rẹ lati di aarẹ orilẹ-ede yii ko le wa si imuṣẹ fun un, ko tiẹ le dibo wọle ninu ijọ rẹ lai tii mẹnuba Naijiria.
"To ba ni owo, ko na owo naa lati fi ran awọn alaini to wa ninu ṣọọṣi rẹ, dipo ko maa fi akoko rẹ ṣofo danu lasan.
"Tunde Bakare ni lati fi ọkan ara rẹ balẹ, ko si gbagbe ala rẹ lati di aarẹ orilẹ-ede Naijiria, ko si gbajumọ iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun ran an lati ṣe e. Ko lọ waasu ihinrere, ko jeere ọkan fun Kristi."
No comments:
Post a Comment