Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta àtààbọ̀ làhámọ́ DSS, wọ́n tú Lady K sílẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 24, 2021

Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta àtààbọ̀ làhámọ́ DSS, wọ́n tú Lady K sílẹ̀


Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ orilẹ-ede yii, iyẹn
Department of State Services ti tu awọn meji yooku to wa lahamọ wọn ninu awọn ọmọlẹyin Oloye Sunday Adeyẹmọ, Igboho, eyi ti gbajugbaja akọroyin nni, Lady K naa wa lara wọn silẹ layọ ati alaafia.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii ni ileeṣẹ DSS lọ kọlu ile Igboho to wa ni Ṣoka, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti wọn ti ko awọn ọmọ ẹyin ọkunrin naa ti ko din ni mejila.
 
Lẹyin oṣu kan ati ọjọ diẹ ni ile-ẹjọ labẹ akoso Onidajọ Obiora Egwuatu paṣẹ pe ki wọn gba beeli gbogbo wọn, ṣugbọn to jẹ mẹwaa pere ni wọn lanfaani lati jade, to si ku Jamiu Noah Oyetunji ati Amudat Habibat Babatunde, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Lady K nibẹ, iyẹn lọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ.
 
DSS releases two Igboho aides after 114 days in custody 
 
Agbẹjọro Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi fidi iroyin yii mulẹ lọjọ kejilelogun, oṣu ti a wa yii pe awọn meji to ku naa ti pada gba ominira kuro lahamọ DSS.
 
Ọlajẹngbesi wa sọ pe bi ohun gbogbo si ṣe n lọ lọwọ, awọn ko tii ni sọrọ kankan sita bayii, nitori awọn idi pataki kọọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI