Mi ò jáde du ipò Ààrẹ mọ́ lọ́dún 2023 jàre, mo ti gba kámú - Yahaya Bello ti sọ̀rọ̀ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 5, 2021

Mi ò jáde du ipò Ààrẹ mọ́ lọ́dún 2023 jàre, mo ti gba kámú - Yahaya Bello ti sọ̀rọ̀ o


Gomina Yahaya Bello, tipinlẹ Kogi ti sọ pe gbogbo erongba oun lati jade du ipo aarẹ orilẹ-ede yii loun ti gbe ju silẹ bayii, bo tilẹ jẹ pe awọn araalu ti wọn nigbagbọ ninu oun lo n sọ pe koun jade du ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
 
Bello ti ko fi erongba rẹ lati du ipo naa lọdun 2023 pamọ  sọ laipẹ yii pe awọn ọmọ Naijiria ni wọn n pe oun lati jade du ipo ọhun.

Ṣaaju akooko yii lo ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn amuyẹ loun ni, eyi to jẹ koun kaju oṣuwọn lati di aarẹ, ati lati ṣe daadaa nipo naa, paapaa nipa jijẹ ki iṣọkan, ifẹ jọba.
 
“Awọn ọdọ, awọn obinrin, pelu awọn ọtọkulu lawujọ ni wọn n fẹ ki n jade du ipo aarẹ lọdun 2023. Mo si ro pe o ti to akooko lati ṣagbeyẹwo ẹni to kaju oṣuwọn, ati ẹni to le ṣiṣẹ naa. Tani yoo mu iṣọkan wọ orilẹ-ede yii? Mo si ro pe o lohun ti wọn n ri, ti wọn fi n sọ pe ki n jade du ipo lati mu orilẹ-ede yii bọ sipo.”

Ọkan lara awọn kọmiṣanna to sunmọ Yahaya Bello nipinlẹ naa, lakooko to n ba akọroyin Daily Independent sọrọ sọ pe gomina naa ti yi ipinnu rẹ pada, nitori bi wọn ṣe n sọ pe awọn ẹkun Guusu lo ni ipo ọhun.
 
Kọmiṣanna naa sọ pe, pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, o ṣee ṣe ki ẹgbẹ oṣelu APC fa oludije sipo aarẹ naa kalẹ lati ẹkun Guusu orilẹ-ede yii.
 
O ni ibi ti wọn fori ipade tawọn gomina ẹkun Guusu orilẹ-ede yii, iyẹn Southern Governors’ Fo­rum (SGF) ni lati ṣiṣẹ tako ẹgbẹ oṣelu to ba fẹẹ yan oludije sipo naa lati ẹkun Ariwa, eyi to lo jẹ ifasẹyin fun ipinnu Gomina Bello, bo tilẹ jẹ pe ko tii sọrọ naa sita funra rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI