Mọ bọ̀wọ̀ gidigidi fáwọn olùkọ́, àwọn ni ilẹ̀kùn àṣẹyọrí gbogbo àgbáyé - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 5, 2021

Mọ bọ̀wọ̀ gidigidi fáwọn olùkọ́, àwọn ni ilẹ̀kùn àṣẹyọrí gbogbo àgbáyé - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe awọn olukọ ni ilẹkun aṣeyọri fun gbogbo agbaye, ati pe, bi ko ba si olukọ, inu aginju ni gbogbo agbaye ko ba wa titi dasiko yii.
 
Lonii, ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, to jẹ ayajọ ọjọ awọn olukọ kaakiri agbaye ni AbdulRazaq sọrọ naa, to si loun o le gbagbe wọn titi lai, nipa ipa ti wọn n ko ninu idagbasoke orilẹ-ede.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita lonii lorukọ gomina, o sọ pe:
 
“Lọjọ oni, ati ni gbogbo igba, Mo fi ibọwọ mi ranṣẹ, mo si gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn olukọ wa ti wọn sa gbogbo ipa wọn lati fi gbe awọn aṣaaju dide kaakiri oniruuru ẹka nile aye yii. Ile aye wa ko ba dabi aginju aimọkan, bi kii ba a ṣe ipa tawọn olukọ ko.
 
“Mo fi n da awọn olukọ wa loju nipa ileri wa lati fi ọrọ awọn olukọ si ipo akọkọ. Laipẹ, awọn alakoso Kwara State Universal Basic Education Board maa gbe awọn lẹta igbega fawọn olukọ sita, ti wọn yoo si jẹ igbadun to tọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI