Ṣe ni ọrọ di boolọ o yago lọna loru ọjọ Abamẹta Satide mọjumọ Sannde, Aiku ana, nigba ti wọn lawọn agbebọn kan yawọ ṣọọṣi Kerubu ati Serafu to wa ladugbo Ọna-Ara, Oju-Irin, iyẹn lagbegbe Ọbada-Oko, ipinlẹ Ogun.
Awọn ti ko din ni mẹta la gbọ pe awọn ajinigbe jigbe salọ ninu ṣọọṣi naa, ti a si tun gbọ pe owo ti ko din ni miliọnu mẹfa naira lawọn ajinigbe naa n beere lakooko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe asiko ti awọn eeyan naa n ṣe iṣọ-oru lọwọ lawọn ajinigbe naa yawọ inu ṣọọṣi ọhun pẹlu ibọn, ti wọn si ji eyan mẹta gbe nibẹ.
Ifẹoluwa Alani-Bello, Adebare Ọduntan ati Mary Oliyide ni orukọ awọn mẹta tawọn agbebọn naa jigbe lọ lasiko iṣọ oru ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ti wọn si ni loootọ lo ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn ikọ ọlọpaa to n ri si ijinigbe nipinlẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ, bẹẹ si ni wọn ti darapọ mọ awọn ti Ọbada-Oko ti ijinigbe naa ti ṣẹlẹ, ireti si wa pe wọn yoo ri wọn laipẹ.
Ọlọpaa waa sọ pe ohun tawọn n kilọ rẹ ree o, pe kawọn oniṣọọṣi yee lọọ maa ṣejọsin ninu igbo, ki wọn maa ni iṣọ oru lawọn n ṣe. O lawọn ti kilọ fun wọn pe bi wọn yoo ba tiẹ lọ sori oke eyikeyii fun adura, ki wọn jẹ kọlọpaa mọ, ki wọn le daaabo bo wọn, ohun lo delẹ bayii ti awọn ajinigbe n beere owo tabua yẹn.
Ṣugbọn ọrọ ti ṣọọṣi Kerubu yii ko ti i kuro nilẹ ti iroyin tun fi gbode pe wọn tun ti ji obinrin kan gbe ni ṣọọṣi ‘Light Apostolic Church’, eyi to wa labule Ṣobubi, l’Ọbada-Oko kan naa.
Titi ta a fi pari iroyin yii, awọn to jiiyan gbe ni ṣọọṣi Light Apostolic Church yii ko ti i kan sawọn ẹbi obinrin naa, wọn ko ti i sọ iye ti wọn yoo gba ki wọn too tu u silẹ.
No comments:
Post a Comment