Ojú ọ̀nà àti gba ògo wa padà la wà, pàápàá lọ́nà ètò ẹ̀kọ́ - Ìjọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Thursday, October 28, 2021

Ojú ọ̀nà àti gba ògo wa padà la wà, pàápàá lọ́nà ètò ẹ̀kọ́ - Ìjọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'Ọjọru, Wẹside to kọja yii ti sọ pe oju ọna lati gba ogo wọn to ti sọnu lati ọdun pipẹ pada, paapaa lẹka eto ẹkọ lawọn wa.
 
Akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jubril, to ṣoju gomina lo sọrọ yii nibi eto ti wọn ṣe lati fi da olukọ labẹ Teaching Service Commission (TESCOM).

Ọjọgbọn Jubril sọ pe nnkan tawọn ba lọdun 2019 ko ṣee gbọ seti, nitori pe iwa 'ko kan mi' nijọba tẹlẹ n hu, bẹẹ si ni wọn tun ki ọrọ oṣelu bọ gbigba awọn olukọ sẹnu iṣẹ.

O tẹsiwaju pe iwa imọtara-ẹni to n ba wọn kaakiri lo jẹ kí wọn maa sọ pe awọn ara Kwara ṣe aṣiṣe lati dibo le wọn danu lọdun 2019.

"Labẹ akoso wọn ni Kwara ṣe sọ ogo rẹ nu. Eto ẹkọ gidi parun labẹ akoso wọn. Eyi ku diẹ kaato."


No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI