Alukoro ẹgbẹ ojulalakanfinṣọri lorilẹ-ede yii, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, VGN, Ọgbẹni Nureni Olanrewaju Adedoyin ti kọwe fipo rẹ silẹ lojiji, eyi to n ya pupọ awọn eeyan lẹnu titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii la gbọ pe Adedoyin kọwe fipo rẹ silẹ, to si ni kii ṣe pe oun kuro ninu ẹgbẹ eleto aabo naa patapata.
Ninu iwe ti ọkunrin naa to ti figba kan ri jẹ ọga agba VGN nipinlẹ Ogun kọ lati fipo rẹ silẹ, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lana, ọjọ Aje, Mọnde, o ṣalaye pe ipo toun di mu gẹgẹ bi alukoro ko si ninu iwe ofin VGN.
Adedoyin tẹsiwaju pe boun tilẹ jẹ pe pẹlu idunnu ati ayọ loun fi gba ipo alukoro, iyẹn Public Relations Officer, PRO nigba naa, ṣugbọn toun ko tete ṣe akiyesi rẹ.
O nigba toun tun pada gbe iwe ofin naa yẹwo daadaa, loun ṣakiyesi pe ipo to farapẹ ipo to wa ninu iwe ofin ti wọn fi da VGN silẹ kii ṣe alukoro, bi ko ṣe akọwe iroyin, iyẹn Publicity Secretary.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ ọga agba ẹgbẹ VGN, Usman Muhammad Jahun fun igbagbọ to ni ninu ẹ lati di ipo naa mu, to si gba gbogbo awọn adari ẹgbẹ naa lamọran lati tun agbeyẹwo iwe ofin naa ṣe lati le faaye silẹ fun ipo alukoro.
No comments:
Post a Comment