Amúgbálẹ́gbẹ́ gómìnà Kwara kú lójijì, ẹ gbọ́ ohun tí AbdulRazaq sọ nípa ikú rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Friday, November 12, 2021

Amúgbálẹ́gbẹ́ gómìnà Kwara kú lójijì, ẹ gbọ́ ohun tí AbdulRazaq sọ nípa ikú rẹ̀


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ ẹsin Kristẹni, Ọmọwe Samuel Oluṣẹgun Adedayọ, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to gbagbọ gidi ninu ẹsin naa.

O ni Ọmọwe Adedayọ jẹ akikanju to farabalẹ, ẹni to tun ni iwa tutu ati itẹriba, eyi to mu ki wọn yan an lati di ipo naa mu, paapaa gẹgẹ bi ipa rere to ti ko lawujọ Kristẹni.

AbdulRazaq jẹ ko di mimọ ninu atẹjade ibanikẹdun to gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye wi pe ọkan pataki lara awọn to nigbagbọ ninu afojusun ijọba yii nipa 'OTOGẸ' ni oloogbe naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI