Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì, kò sí ìkùnsínú láàárín èmi àti AbdulRazaq o - Tinubu pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 24, 2021

Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì, kò sí ìkùnsínú láàárín èmi àti AbdulRazaq o - Tinubu pariwo síta


Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lorilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe ki gbogbo awọn ẹlẹnu karikasọ lọ dakẹ ọrọ ti oju wọn ko to nipa ajọṣepọ to wa laaarin oun pẹlu gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman Abdulrazaq, nitori pe ko si ikunsinu ati tabọ laaarin awọn mejeeji.

Tinubu sọ pe lati ọdun 1999 loun pẹlu AbdulRazaq ti n ni ajọṣepọ to dan mọnran papọ, ti ko si sohun to lẹ yẹ ibaṣepọ wọn.

Laipẹ yii ni awuyewuye ọhun n kaakiri wi pe ẹyin igun Lai Mohammed ni Tinubu wa, ati pe ko ni nnkankan ṣe pẹlu Gomina AbdulRazaq.

Aṣiwaju Tinubu, gẹgẹ bi ọkan lara awọn to sunmọ-ọn daadaa ṣe sọ, sọ pe ko sẹni to le sọ pe Gomina Abdulrazaq ko mu idagbasoke ba ipinlẹ Kwara, nitori pe ipa rere lo n ko kaakiri awujọ.
 
O ni ohun kan ṣoṣo tawọn eeyan n binu si ni pe ko jẹ ki wọn mọ bo ṣe n ṣiṣẹ idagbasoke, ti kii sii jẹ ki wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ si, eyi to ni ko to nnkan babara ti wọn le maa fi binu.

Bakan naa ni Ọnọrebu Saheed Popoọla, ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara to n ṣoju ẹkun Balogun/Ojomu, nigba to n sọrọ lori redio kan lọjọ Iṣẹgun, Tuside ana sọ pe gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ APC ko ni pẹ ẹ lọ soko igbagbe, nitori pe apẹẹrẹ ti n foju han.
 
O wa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ti inu n bi lati jẹ eburẹ, ti wọn si bu omi suuru mu, ati pe ki wọn tubọ fọwọsowọpọ pẹlu Gomina AbdulRazaq.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI