Ẹ tọwọ́ àwọn ọmọ yín bọ aṣọ o, ẹ̀wọ̀n kìí ṣe erémọdé - RRS pariwo síta fáwọn òbí àti alágbàtọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 2, 2021

Ẹ tọwọ́ àwọn ọmọ yín bọ aṣọ o, ẹ̀wọ̀n kìí ṣe erémọdé - RRS pariwo síta fáwọn òbí àti alágbàtọ́


Ileeṣẹ eleto aabo pajawiri, Rapid Response Squad, RRS nipinlẹ Eko ti gba awọn obi ati alagbato lamọran lati kilọ fawọn ọmọ wọn, tabi ki wọn tọwọ wọn bọ aṣọ lori iwa ọdaran ti wọn n hulojoojumọ.
 
Wọn ni bawọn ọmọde ati ọdọ ṣe n uwa ọdaran lakooko yii n kọ awọn lominu pupọ, eyi ti wọn sọ pe atunṣe gbọdọ wa si.
 
Ninu atẹjade ti RRS gbe jade laipẹ yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti sọ pe awọn ti ọwọ n tẹ lori iwa ọdaran lakooko yii ni ọjọ ori wọn ko ju ọdun meedogun si mẹtadinlọgbọn lọ, to si ni ogbologbo adigunjalẹ ni wọn.
 
Lara awọn iṣẹ to ni wọn n ṣe ni jija foonu gba, jija baagi ati pọọsi gba, jija mọto gba, yiyọ owo lapo awọn eeyan laimọ, lilu jibiti, gbigbe oogun oloro ati bẹẹbẹẹlọ.

Wọn ni ẹwọn ọsu mẹrin, mẹfa, mẹsan-an ati bẹẹbẹẹlọ kii ṣe kekere, to si le din ọjọ iwaju awọn tọwọ n tẹ naa ku.
 
Diẹ ree lara awọn tọwọ tun ṣẹṣẹ tẹ lori iwa ọdaran ti wọn n sọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI