Èmi náà máa ṣe ìgbéyàwó tuntun láìpẹ - Musiliu Haruna Iṣọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 30, 2021

Èmi náà máa ṣe ìgbéyàwó tuntun láìpẹ - Musiliu Haruna Iṣọla


Gbajugbaja agba olorin apala nni, Alaaji Musiliu Haruna Iṣọla ti sọ pe oun naa ti ṣetan bayii lati ṣe igbeyawo tuntun laipẹ.

O ni ki awọn eeyan to ro pe agba olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal nikan ma ro pe ẹnikan ṣoṣo to le kọrin laaarin awọn agba olorin niyẹn.

Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Alaaji Haruna Iṣọla sọrọ yii jade, nibi eto ti ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ gbe kalẹ nilu Abẹokuta, nibi ti wọn ti n gba mayegun ilẹ Yoruba, Alaaji Wasiu Ayinde lalejo.

Eto naa ti wọn pe akọle rẹ ni Time Out with the Broadcasters, K1 De Ultimate lo waye ninu gbọngan ayẹyẹ kan to wa ninu ọgba ile ikawe Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta.

Nigba to n kọrin, Alaaji Haruna Iṣọla sọ pe "Emi naa máa ṣe igbeyawo laipẹ, ki ẹ ma ro pe K1 nikan ni. Musiliu Bẹbẹ lo maa ṣe amugbalẹgbẹ ọkọ iyawo, nigba ti Ere Asalatu yoo kọrin lọjọ naa."

Pupọ awọn to wa nibẹ ni wọn sọ pe ko daju pe agba onkọrin Apala naa yoo ṣe igbeyawo gẹgẹ bo ṣe sọ. Wọn lo kan fi ṣe ẹfẹ lasan ni, lati fi gbe ọkan awọn eeyan soke.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI