Ìjọba Kwara fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ sáwọn ọ̀dọ́, ìpàdé ńlá ni wọ́n fẹ́ẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 12, 2021

Ìjọba Kwara fẹ́ẹ́ gbọ̀nà àrà yọ sáwọn ọ̀dọ́, ìpàdé ńlá ni wọ́n fẹ́ẹ́ fi bẹ̀rẹ̀


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe awọn ti ṣetan lati ṣagbatẹru akanṣe eto ipade nla fawọn ọdọ ipinlẹ naa, lojuna lati jẹ ki wọn wa ninu iṣakoso ijọba.


Ogunjọ, oṣu yii la gbọ pe ọfiisi amugbalẹgbẹ agba fun gomina lori ọrọ awọn ọdọ fẹẹ ṣagbatẹru eto ipade nla naa ti wọn pe ni 'Statewide Town-Hall Meeting' nijọba ibilẹ Ariwa Kwara.
 
Ninu atẹjade ti Arabinrin Kaosarah Adeyi to jẹ amugbalẹgbẹ agba fun gomina lori ọrọ awọn ọdọ fi sita l'Ọjọbọ, Tọside ana lo ti sọ pe awọn fẹ kawọn ọdọ naa ni ipa, ati lati ro wọn lagbara, ki wọn si le lẹnulọrọ nipinlẹ naa ni.

Akori eto naa ni wọn pe ni "Kwara under AA: Our Strides and Future Plans", ni wọn tun gbe kalẹ lati jẹ ki ijọba sunmọ awọn ọdọ ju ti atẹyinwa lọ.
 
Bode Saadu to wa nijọba ibilẹ Moro, Ariwa Kwara ni eto pataki naa ti fẹẹ waye.

Lẹyin eyi la gbọ pe wọn yoo kede ibi ti eto naa yoo ti waye fun aarin gbungbun ipinlẹ Kwara ati Guusu Kwara, eyi ti yoo jẹ gbogbo ọdọ ipinlẹ naa jẹ anfaani rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI