INEC kéde Soludo gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 10, 2021

INEC kéde Soludo gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tuntun


Ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii, Independent National Electoral Commission (INEC) ti kede Ọjọgbọn Chukwuma Charles Soludo ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance (APGA), gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina to waye nipinlẹ Anambra lopin ọsẹ to kọja.


Oludari ajọ naa to ṣagbatẹru eto idibo ọhun, Ọjọgbọn Florence Obi to jẹ fasiti ipinlẹ Calabar lo kede Solude gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori laago meji ku iṣẹju mẹwaa aarọ oni, Ọjọru, Wẹside.

Obi sọ pe lẹyin tawọn ṣakojọpọ gbogbo ibo to waye kaakir ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ ọhun, awọn rii pe Soludo ni ibo rẹ kun julọ si ti awọn oludije lẹgbẹ yooku bii PDP ati APC.

APGA ni ibo 112, 229, nigba ti PDP ni 53,807, ti APC si ni ibo.

Obi tẹsiwaju pe gbogbo ibo to ṣoju ṣaara tawọn oludibo di jẹ 241,523; awọn ibo to ni kọnun-kọhọ ninu jẹ 8,108, nigba ti apapọ ibo ti wọn di jẹ 249,631.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI