Ó ṣẹlẹ̀ o! Samuel gbé òògùn apẹ̀fọn jẹ l'Óṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 8, 2021

Ó ṣẹlẹ̀ o! Samuel gbé òògùn apẹ̀fọn jẹ l'Óṣogbo


Ko tii sẹni to le sọ pato idi ti gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ samuel Marvellous ṣe deede gba ẹmi ara rẹ lojiji nilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe ṣe ni Samuel gbe oogun apẹfọn ti wọn n pe ni Sniper mu, to si ṣe bẹẹ gba ọrun alakeji lọ.

Adugbo kan ti wọn pe ni Isalẹ Aro, to wa ni adojukọ ileewe girama ti OSCO nilu Oṣogbo niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aiku, Sannde, ana.

Wọn ni ọkan lara awọn ti Samuel jọ n gbe inu ile kan naa lo gbọ ohun rẹ nibi to ti n jẹ irora, to si sare wọ yara rẹ lọ lati mọ nnkan to ṣe e.

Si iyalẹnu, wọn ni ori idubulẹ ni ẹni naa ti ba Samuel, to si ku diẹ ko ku. Ẹni yii lo pariwo sita, to fi di pe awọn eeyan sare wa, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu fun itọju lati doola ẹmi rẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ itọju ti wọn fun Samuel, ọmọ ilẹ Ibo nni, o sẹni laanu wi pe o pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra laaarọ ono, ọjọ Aje, Mọnde.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI