Ọláyínká Fáfolúyì gba àwọ́ọ̀dú tuntun tí kò wọ́pọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 10, 2021

Ọláyínká Fáfolúyì gba àwọ́ọ̀dú tuntun tí kò wọ́pọ̀


Ọjọ manigbagbe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla tun jẹ ninu itan fun oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq lori ọrọ iroyin ori ayelujara, Kọmureedi Ọlayinka Fafoluyi ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Solace.

Idi ni pe ọjọ naa lo gba awọọdu ti ko wọpọ, gẹgẹ bi imọriri awọn ipa to ti ko lawujọ awọn ọdọ,, eyi to fi n jẹ awokọṣe rere fawọn ọdọ to n bọ lẹyin.

Awọọdu naa ti wọn pe ni Young Achievers Award ni wọn fun un lati fi ṣe koriya fun awọn iṣẹ takuntakun, ati igbarukuti awọn ọdọ lawujọ orilẹ-ede yii, paapaa nipinlẹ Kwara.

Nigba to n fi imọriri rẹ han lori awọọdu ọhun, Fafoluyi sọ pe oun ko le ṣai dupẹ lọwọ awọn mọlẹbi ati ọrẹ ti wọn n gbadura, ti wọn si tun nifẹ oun ni gbogbo igba, eyi to jẹ ki awọọdu naa tọ soun.

O lo jẹ ohun to dun mọ oun ninu wi pe awọn eeyan le mọ riri ipa toun n ko lati gbaruku ti awọn ọdọ, idagbasoke agbegbe ati ijọba rere, bẹẹ lo sọ pe oun gbe oṣuba kare fun eeyan, paapaa julọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq toun foun lanfaani lati sin awọn eeyan oun.

Siwaju sii lo dupẹ lọwọ Ọgbẹni Rafiu Ajakaye ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ akọroyin ijọba nipinlẹ Kwara, ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ onitẹsiwaju patapata fun atilẹyin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI